Sẹnetọ Amosun ṣalaye bi wọn yoo ṣe di awọn ẹru ounjẹ naa |
Lati le jẹ kawọn eeyan ri ounjẹ jẹ fun ti igbele koronafairọs to n lọ lọwọ nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun nile igbimọ aṣofin niluu Abuja, iyẹn Ogun Central, ti bẹrẹ si ni pin ẹbun ounjẹ fawọn araalu, lati le maa mu nnkan sẹnu.
Ipin ounjẹ naa to bẹrẹ lati Ọjọbọ, Tọsidee, ana, la gbọ
pe wọn ti n gbe lọ kaakiri awọn wọọdu, eyi ti wọn bẹrẹ ni ijọba ibilẹ Ifọ.Awọn
ounjẹ ti wọn n pin naa la ti irẹsi, ororo, mimie atawọn nnkan mii-in.
Lọgan ti wọn si ti gbe de awọn wọọdu to wa ni ijọba ibilẹ
Ifọ, lawọn eeyan ibẹ ti n tẹwọgba, ti wọn si n dupẹ lọwọ ẹni to ṣẹṣẹ fipo
gomina silẹ nipinlẹ Ogun pe o ṣeun, binu ọpọ awọn eeyan ti wọn jẹ anfaani ṣe
dun to ni wọn ṣe n fi ọkan wọn gbadura fun Sẹnetọ naa.
Ijọba ibilẹ Abeokuta South ati ti Abẹokuta North, la gbọ
pe wọn pin ounjẹ naa fun lonii, ki awọn to pin ounjẹ naa to fi mọto wọn gbe
ounjẹ naa de lawọn to wa ni wọọdu ti wa ni imurasilẹ, ti wọn reti wọn.
Bẹẹ lawọn eeyan naa fi adura ranṣẹ si Sẹnetọ Amosun fun oore
nla to ṣe fun wọn, ti ko jẹ ki ebi pawọn sinu ile. Ohun ta a tun gbọ ni pe
iranwọ ti Amosun n ṣe yii ki i ṣe agbegbe ẹ nikan lo fẹẹ ṣe si, wọn ni yoo nawọ
ẹ de awọn ẹkun yooku to wa nipinlẹ Ogun.
Ọkan lara mọto to kẹru naa lọ sawọn ijọba ibilẹ |
No comments:
Post a Comment