Awọn eeyan agbegbe Abẹokuta South, tipinlẹ Ogun ti dupẹ pupọ lọwọ Ọnarebu Lanre Ẹdun, to n ṣoju wọn nile igbimọ aṣoju- ṣofin niluu Abuja lori bo ṣe n pese ounjẹ fun wọn latigba ti ọrọ korona fairọs ti bẹrẹ lagbaye.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Onarebu yii lẹni akọkọ ti yoo kọkọ fawọn
eeyan ẹ lounjẹ, ko tiẹ to di pe konile-o-gbele bẹrẹ, koda kawọn oloṣelu yooku
to ni lọkan lati ṣe fawọb eeyan wọn.
Iwadii fi ye wa pe lọsọọsẹ lawọn eeyan ẹ n ri nnkan gba
bi ounjẹ lọ sile, eyi ti wọn ni Ọnarebu Lanre Ẹdun lo n satọna ẹ, idi niyii tawọn
eeyan agbegbe ẹ fi n fẹmi imoore han si pe aṣaaju rere to ṣe fọkan tan ni ọkunrin
naa.
Lara awọn eeyan to ba oniroyin wa sọrọ ni ṣapejuwe Lanre Ẹdun,
gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu, to si maa n ṣoore fawọn eeyan lai fi ti oṣelu ṣe.
Wọn ni ounjẹ ti ọkunrin naa fawọn lati maa jẹ lakooko
konile-o-gbele yii lo jẹ pe gbogbo awọn to wa lagbegbe Abẹokuta bẹrẹ lati wọọdu
ni wọn jẹ anfaani ẹ.
Bẹẹ lo ṣe jẹ pe awọn ti ki i sọmọ ẹgbẹ oṣelu APC naa ri
ninu anfaani naa, ti wọn si ri nnkan mu lọ sile, eyi nikan kọ, wọn lo tun gbe
ounjẹ kalẹ ninu eto ti Ayinla Ẹgba n ṣe, tawọn eeyan si lọ n gba.
Awọn ẹbun bi irẹsi tutu, ẹwa, gaari atawọn nnkan tẹnujẹ
mii in, ni wọn lo n pin fawọn araalu, ti wọn si n sadura fun-un. A tiẹ tun gbọ
pe ki i ṣe akoko yii nikan ni ọkunrin oloṣelu naa maa n ran awọn eeyan lọwọ,
latigba to ti dori ipo ni, gbogbo ileri ẹ ni wọn lo si n muṣẹ fawọn.
No comments:
Post a Comment