Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludasilẹ ajọ kan to n ri si
anfaani lati kọ ọjọ iwaju, tawọn oloyinbo pe ni Building opportunities for Tomorrow,
BOT, ti ṣe agbekalẹ ẹbun fawọn ẹgbẹrun meji, to ku diẹ kaato lawujọ fun ti
konile-o- gbele to n lọ lọwọ latari ti arun korona fairọs.
Gẹgẹ bi atẹjade eyi ti wọn fi sọwọ si wa, ounjẹ atawọn
ohun elo lo wa ninu apo ti wọn gbe fawọn eeyan naa, ki wọn le ri jẹ. Lara ẹ ni
irẹsi tutu, sẹmo, gaari, ẹwa,ororo ati maggi.
Ọtẹgbẹyẹ ṣeto nnkan wọnyi fawọn eeyan naa gẹgẹ bi ipa tiẹ
lati ran awọn to ku diẹ kaato fun, ki wọn le maa ri nnkan jẹ lakooko ti
konile-o- gbele yii fi wa nita, nitori arun korona fairọs to gbode yii.
O wa lo akoko naa lati sọ fawọn araalu lati tẹle ofin tijọba
pa laṣẹ fun wọn lori ti arun korona ọhun, pe ki onikaluku duro sile titi ti wọn
yoo fi pari igbele naa.
O ni oun mọ pe ọpọ awọn eeyan ni inu wọn ko ni dun si
igbesẹ nitori atijẹ, o jẹ ki wọn mọ pe gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ yii fun igba diẹ
ni ati pe laipẹ laijina ni gbogbo ẹ yoo dohun itan.
No comments:
Post a Comment