Gẹgẹ bi
konile-o-gbele ṣe n tẹsiwaju tijọba ipinlẹ Ogun si n sagbara lati ma jẹ ki arun
naa gbalẹ, eyi to fa igbele fawọn eeyan, titi di akoko yii lawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ fi
n dide iranlọwọ fun ijọba lati le sa ipa wọn.
Lọsẹ to kọja
yii ni igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele, fi gba
awọn alejo ni ọfisi ẹ nibi ti wọn ti mu ẹbun ọkan-ọ-jọkan wa lati fun iranwọ
fawọn araalu, ki igbele ti wọn wa ko ma jẹ ko sun wọn.
Lara awọn ẹbun
ti igbakeji Gomina gba wọle lọjọbọ, Tọsidee, osẹ yii ni moto pajawiri tawọn
oloyinbo n pe ni Ambulance,ounjẹ loriṣiriṣi,ati owo tawọn eeyan ọhun fi
fatilẹyin wọn han si ijọba lati koju arun korona fairọs yii.
Nigba to n gba
awọn ẹbun naa lorukọ ijọba, Nọimọt Salakọ, fi ẹmi imoore ẹ han fawọn to mu awọn
ẹbun naa wa si apo ijọba pẹlu bi nnkan
ṣe ri lakooko yii wọn tun le ṣe awọn nnkan wọnyii.
O fikun ọrọ ẹ
pe loorekoore nijọba yoo maa sa ipa lati le jẹ ki ajọṣepọ to danmọran wa laarin
wọn ati awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ, awọn ẹlẹsin atawọn ileeṣẹ lawujọ, ki idagbasoke tun
fi le jọba.
Obinrin naa tun
sọ pe aimọye owo nijoba ipinlẹ yii ti na lori wahala ti arun korona fairọs da
silẹ lati le ri pe abo ati ilera to peye wa fawon olugbe ipinlẹ naa.
O ni lara awọn
igbesẹ tijọba ti gbe ni fifun awọn eeyan to ku diẹ kaato lawujọ ni ounjẹ kaakiri
ijọba ibilẹ Ogun to wa nipinlẹ ọhun, o wa lo akoko yii lati fi tun pe awọn
ẹlẹyinju aanu lawujọ pe kawọn naa sa ipa wọn fun iranlọwọ awọn araalu.
Ko to to akoko yii, ni ọga agba
nileesẹ Ogun Osun River Basin Authority, Ọgbẹni Olufemi Odumosu, ti sọ pe awọn
ṣagbekalẹ awọn nnkan ọgbin bii igba kireeti ẹyin, omi inu ọra mimu ẹgbẹrun lọna
ogun,gaari gẹgẹ bi ipa tawọn naa fawọn araalu fun ti akoko ta a wa yii. O ni
aimọye ẹmi ni korona fairọs yii ti mu lọ, to si tun ti sakoba fun eto ọrọ aje
wa pẹlu.
Lori ipade ẹrọ ayelujara ni Igbakeji
gomina ti dupẹ lọwọ ileesẹ Procter and Gamble, fun bi wọn ṣe gbe ọṣẹ lorisirisi
towo ẹ to miliọnu marun un abọ naira.
Bakan naa ni ajọ awọn Imaamu naa gbe
miliọnu meji abọ naira silẹ.
Ileeṣẹ to n
muna wa Ibadan Electricity Distribution
Company, naa fi miliọnu naira kan silẹ, Ileeṣẹ to n ṣe simẹnti Lafarge
Africa Plc, ti Arabinrin Folake Odegbami, ṣaaju naa gbe mọto pajawiri silẹ fun
ti korona fairọs yii naa ni.
No comments:
Post a Comment