Kọmisanna feto isuna nipinlẹ Ogun, Dapọ Okubadejọ fawọn eeyan ẹ lẹbun ounjẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 11 April 2020

Kọmisanna feto isuna nipinlẹ Ogun, Dapọ Okubadejọ fawọn eeyan ẹ lẹbun ounjẹ 
Fun ti igbele kan-an pa to wa lode nipinlẹ Ogun, nitori ọrọ arun korona fairọs, Dapọ Okubadejọ, kọmisanna feto isuna nipinlẹ Ogun, ti fawọn eeyan ẹ to wa lagbegbe Ijẹbu, fawọn eeyan to ku diẹ kaato, ki wọn le ri ohun jẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, apo baagi irẹsi aadọjọ, ti ọkọọkan ẹ jẹ kilo aadọta, ni kọmisanna ọhun ni ki wọn ko lọ si ljẹbu-Ode, Odogbolu ati ljẹbu North East, nigba to fun wọn ni paali ogun ti ọṣẹ ti wọn fi n fọwọ iyẹn sanitizers, apo baagi ẹwa ogun, ọgọta apo gaari ati maalu mẹta lo gbe lọ si agbegbe tiẹ gan-an fawọn eeyan to wa nibẹ.
.
Niigba to n ṣagbekalẹ awọn ẹbun naa fawọn eeyan Oloja–Bara, Oke-nla, Arowolo, Imoru ati Ondo road nijọba ibilẹ Ijebu Ode, Ọnarebu Olugbile, alaga ijọba ibilẹ Ijebu-Ode, to ṣoju kọmisanna naa lo ti sọ pe lara ipa iranwọ ti ọkunrin naa ṣe lati fi ran ipinlẹ yii lọwọijọba yii lọwọ lori igbogun ti korona fairọs to gbode.O ni ‘ Iṣẹ ajumọṣe wa ni lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati gbogun ti korona fairọs lawujọ, mo wa rọ yin lati tele  ofin ma-sun-mọ- ara-ẹni. Ka maa fọwọ wa pẹlu ọṣẹ loorekoore. Ki a si ran awọn to ku diẹ kaato lawujọ lọwọ.

O ni isakoso Gomina Dapọ Abiodun  ti ṣiṣẹ takuntakun lori ona ati pese ounjẹ atawọn ohun elo sawọn ijọba ibile ogun to wa nipnlẹ yii.O wa gbadura pe laipẹ yii la maa bori idaamu aifọkanbalẹ korona fairọs naa.

Ninu ọrọ Ọnarebu Ṣẹgun Ọdunọla, to jẹ alaga ijọba ibilẹ Ijẹbu North East, o fi ẹmi imoore ẹ han lori awọn ẹbun ti kọmiṣanna ọhun fun wọn, o wa ṣeleri pe gbogbo awọn to ku diẹ kaato to wa labẹ lawọn yoo pin ẹbun naa fun.


Nigba to n gboriyin fun ẹni to gbe ẹbun naa kalẹ lakooko ti wọn pin ni ojule si ojule Oloritun Bara ti Itun Bara Iṣoku, Oloye Bisiriyi Odukọya rọ awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn jẹ ọmọ ipinlẹ yii lati fi ti Dapọ Okubadejọ ṣapẹẹrẹ rere, ki wọn si fi ifẹ han pẹlu gbogbo eleyii, o ni korona yoo lọ patapata lorileede yii.

Arabinrin Monsurat Asimo, ọkan lara awọn to jẹ anfaani ẹbun naa ni Imoru naa fi idunnu ẹ han pe oun iyalẹnu lo ṣẹlẹ yii, o wa gba awọn eeyan niyanjy lati tẹle ofin tijọba ba la kalẹ fun wọn lati dẹkun arun naa.No comments:

Post a Comment

Pages