Ọba Onitẹtiku tiluu Owode-Ọta gboriyin fun ọga ọlọpaa ẹkun Sango-Ọta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 12 April 2020

Ọba Onitẹtiku tiluu Owode-Ọta gboriyin fun ọga ọlọpaa ẹkun Sango-Ọta


Onitẹtiku tiluu Owode-Ọta, nipinlẹ Ogun, Ọba Ogungbayi Akanni Wasiu ti fi ẹmi imoore ẹ han si ọga ọlọpaa iyẹn DPO, ti ẹku Sango- Ọta, Godwin Idehai atawọn eeyan ẹ lori bi wọn ṣe ṣabẹwo abo ilu si aafin ẹ ninu ọsẹ ta a lo tan yii.

Kabiyesi gboriyin yii lakooko ti ọga ọlọpaa sabẹwo si laafin. O ni pẹlu bi ilẹ ṣe su to ni nnkan bi aago mẹjọ alẹ ojo Ẹti, Furaidee, ni ọga ọlọpaa yii lọọ pẹlu awọn eeyan ẹ kaakiri agbegbe Owode, Ijakọ, Alade, ijoko atawọn ibo mii in tawọn adigunjale ti n da awọn eeyan ibẹ laamu.

O ni akọ iṣẹ lawọn ọlọpaa naa ti n ṣe latigba ti wọn ti mu ibẹru bojo bawọn to n gbe lagbeegbe yii, ti wọn si n fi wọn lọkan balẹ. Bẹẹ naa ni Ọba Onitẹtiku tun lo akoko naa lati dupẹ lọwọ awọn Baales, Oloye, atawọn asaaju agbegbe pẹlu awọn onidagbasoke fun bi wọn ṣe fọwọsowọpọ pẹlu pẹlu awọn ọlọpaa lati kappa awọn ọdaran yii.

Ninu ọrọ ti ọga ọlọpaa, DPO, Godwin Idehai loun naa ti dupẹ lọwọ ọba atawọn eeyan ẹ pe wọn jẹ ọrẹ ọlọpaa, O wa rọ Kabiyesi lati maa dawọn eeyan ẹ lẹkọọ nipa lati ma maa fawọn niroyin ti ko ṣẹlẹ, nitori iru nnkan bẹẹ maa n da wahala silẹ lọjọ iwaju. O wa mu da Onitetiku loju pe gbogbo awọn ọlọpaa to wa lagbegbe naa ni wọn yoo tẹ siwaju lati pese abo fawọn olugbe nigbogbo igba.No comments:

Post a Comment

Pages