Onitẹtiku tiluu Owode-Ọta, nipinlẹ Ogun, Ọba Ogungbayi Akanni Wasiu ti sọ pe ninu abajade ipade to waye lọjọ kẹwaa, oṣu kẹrin, ọdun yii ni aafin ẹ lawọn ti fi ẹnu ko pe titi digba ti igbele konile-o- gbele to wa nita bayii yoo fi kasẹ nilẹ ni oro yoo fi maa jade niluu naa lati fi le arun koronafairọs to n ja gbogbo orileede lọ
Ninu atẹjade
abọ ipade naa lo tun ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan agbegbe naa fun ifọwọsowọpọ
wọn ati atilẹyin ti wọn ṣe lati le jẹ kiluu naa toro. Won ni pẹlu gbogbo nnkan
to n ṣẹlẹ yii ni wọn ti gbawọn eeyan wọn nimọran lati tete maa pa ẹrọ amunawa
wọn,iyẹn jẹnẹreto, ni nnkan bi aago
mẹsan-an alẹ, bẹẹ lawọn to ni ṣọọbu naa tete maa ti ṣọọbu wọn lakooko yii.
Didana sun taya gbọdọ maa waye laaarin
aago mẹsan-an alẹ si mejila oru, ki aye le wa fawọn to n gboro jade, ati pe aye
wa fawọn fijilante lati maa tẹsiwaju oro lẹ ni tiwọn.
Bẹẹ ni wọn rọ
awọn onidagbasoke lati maa mojuto awọn agbegbe wọn, lati le dina awọn
adigunjale to le fẹẹ maa yọ wọn lẹnu. Wọn tun lawọn ṣetan lati le jẹ ki
ibanisọrọ wọn gbooro si, tiru ipade mii in yoo tun waye lọjọ kẹrinla oọu yii ni
aafin bakan naa.
No comments:
Post a Comment