Laipẹ yii ni iya arugbo kan, Iya Saidi onirọba, jade lori
ẹrọ ayelujara to sọ pe nibi ti nnkan buru fun un de,boun ba ri ọkunrin ba oun sun,
ti yoo foun ni ẹẹdẹgbẹta naira, oun ṣetan lati gbe idi oun silẹ nitori ko sowp
ati ounjẹ toun atawọn ọmọ oun yoo jẹ.
Latigba naa lawọn clcyinju aanu ọmọ orileede yii ti n dide
anu, ti wọn fun un lowo ati ounjẹ. Ṣugbọn kin ni kan ni o, ẹnikan ni Ọlọrun lo
fun, to fi di ẹni taye n wo ṣe e loore.
Kọlawọle Adejojo, tọpọ awọn eeyan mọ si Kasnaty, sọrọsọrọ
ori redio, oun ni ẹni naa, nibi to ti n kaakiri igboro bawọn eeyan sọrọ lori konile-o-gbele
to n lọ lọwọ nipinlẹ Ogun, nipa ti arun korona fairọs to tan kalẹ kaakiri lo ti
salabapade obinrin ọhun.
Nigba to n ba oniroyin wa sọrọ lori igbesẹ to gbe lati ma
gbele lakooko konile-o-gbele ọhun, Kasnaty sọ pe loootọ loun ko gbele, nitori
oun ronu nnkan tuntun ni.
O ni “ Ki i ṣe gbogbo eeyan eeyan lo ni anfaani si redio,
bẹẹ lọpọ awọn eeyan to nifẹẹ si redio ni wọn ki i lannfani lati pe wọle lati mọ
nnkan to n ṣẹlẹ nibomii in. Idi niyii ti mo fi ronu ọna ti mo le gba lati ma fi
kan sawọn araalu lakooko korona yii”
Nigba to mẹnuba awọn iriri ẹ latigba to ti n jade, o sọ
pe awọn nnkan toun ti ri lagbara o, ninu iriri ẹ loun ti ri pe ki i ṣe gbogbo
eeyan nijọba le tẹ lọrun, oun ri pe ijọba tẹ awọn eeyan lọrun ṣugbọn awọn ibi
kan wa ti ko ti i de.
Kasnaty tun ṣalaye pe ki i ṣe pe ijọba loun ṣiṣẹ fun o,
oun kan n lọ kaakiri lati mọ bo ṣe n lọ, ninu irikerindo oun nigba to kọkọ bẹrẹ
lati mọ boya konile-o-gbele yẹn tọna.
O ni ‘’Awọn kan sọ
pe ko tọna, awọn kan lebi n pawọn debi pe mo pade Arabinrin kan to sọ fun mi pe
ọjọ kan toun lo nile, ti su oun.o ni ka ni ibi iṣẹ oun loun wa, oun yoo mọ iye
toun ti ri”
Nigba tobinrin yẹn maa sọrọ, o ni toun ba ri ẹgbẹrun lọna
ogun naira lọwọ mi, oun yoo tẹle mi, o ni oun yoo gbe ọmọ dani, boun si gbe ọmọ
dani ko ṣe nnkankan, ki lo mu labare ẹgbẹrun lọna ogun naira wa? O ni ka ni ile
ọti loun wa ni, oun yoo ti mọ iye toun maa ri. O ni ile ti su oun.”
Ọkunrin yii tun sọ pe gbogbo igba ti wọn ba sọ pe koun ma
jade loun maa n jade, gẹgẹ bi oniroyin lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ. Ninu nnkan tawọn
n ṣe, ọpọlọpọ lo ni o n fawọn lowo lati ilu oyinbo lati fawọn eeyan.
O tun tẹsiwaju ‘’Lọjọ Furaidee, to jẹ Good Furaide, irinkerindo
yẹn wa gbe mi lọ si Igboore, nigba ti mo n ṣiṣẹ nibẹ awọn eeyan n sọrọ bi nnkan
ṣe ri laduugbo wọn, mo n ṣe ifọrọwerọ pẹlu arugbo kan, ni mo gbọ ti mama kan sọ
pe kinni, ṣe gbogbo ẹ da ni, boun ṣe wa yii, ko si nnkan toun ko le ṣe, boun ba
ri nnkan, oun a ṣe nnkankan, mo ni ye, kin ni eleyii.
Ni mo ba sunmọ ọn pe kin ni nnkan to sọ, o ni toun ba ri ẹẹdẹgbẹta
naira, oun a dọkọ, mo beeere pe ṣe o si le ṣe kinni bayii, o sọ pe oun le ṣe
nigba toju ara oun ko ranri, o ni o san ju koun lọ jale. Mo beeere pe to ba ki
i mọlẹ to ba hukọ n kọ, o ni rara oun ko le hukọ.’’
O ni boun ṣe ṣe kongẹ obinrin naa niyi toun si gbe sori ẹrọ
ayelujara, bawọn eeyan ṣe n pe oun niyẹn, bawo lawọn ṣe le ṣe,ki iya yii ma ṣe
agbere, ti wọn dide iranlọwọ fun-un, ti okiki ẹ kan kaakiri.
Awọn eeyan fowo ranṣẹ si obinrin naa sinu
akaunti ọmọ ẹ, igbakeji gomina naa fẹbun ranṣẹ, Don Jazzy, awọn onitiata
atawọn yooku lawujọ.
Kasnaty tun sọ pe pẹlu gbogbo ibi toun de awọn araalu pa
ofin konile-o-gbele naa mọ nipinlẹ Ogun,ṣugbọn akiyesi toun ri ni pe nigba toun
lọ si Sango, mo ri pe ero pọ, mo wa beeere pe bawo ni ero ṣe pọ, wọn sọ pe ọja
ni, wọn boya o sunmọ Eko, mo ni ka gba bẹẹ, amọ ni Abẹokuta, Ṣagamu ti mo ti
de, wọn paa mọ ni.
O wa pari ọrọ ẹ pe “”Ki i ṣe pe mo ṣiṣẹ naa fun ijọba, bi
ko ṣe lati lo ọgbọn atinuda lati le jẹ kawọn eeyan mọ wa,keeyan ma duro lori pe
iṣẹ kan lo n ṣe, maa wa ọna tiṣẹ ẹ yoo
fi yatọ fi tẹlomii in. To ba jẹ pe ori redio ni mo duro si ni Iya yẹn la ma ni anfaani
lati pe, to ba tiẹ le pe iru ọrọ to sọ ko le lọ lori redio.
No comments:
Post a Comment