Obinrin arugbo ti wọn pe ni Iya Saidi onirọba to pariwo
sita lakooko ti konile-o-gbele ṣẹṣẹ bẹrẹ pe toun ba ri ọkunrin to le foun ni ẹẹdẹgbẹta
naira oun le gbe abẹ oun silẹ lati ṣe kinni foun, tawọn eeyan si dide aanu si
loju ẹsẹ naa ti ṣe bẹbẹ o
Lọjọ Aiku, Sannde, ni obinrin naa fun agba oṣere onitiata
nni, Alaaji Yekeen Oyedele tọpọ mọ si ẹgbẹrun lọna ogun naira lati fi tọju ara ẹ.
Nile Baba naa to wa ni Itoku ni obinrin naa ati gbajumọ sọrọsọrọ,
ẹni ti Ọlọrun lo fun un iyẹn Kọlawọle Adejojo tọpọ mọ si Kasnaty ti fun agba oṣere
ọhun ti wọn lo ti wa lẹnu aisan tipẹ, ti ko le
jade nile lowo naa.
Nigba ti obinrin yii sọrọ o loun gbe igbesẹ naa lati fi
ran Baba Lẹgba lọwọ nitori pe nigba toun naa wa ninu ailowo lọwọ ti gbogbo ẹ
dojuru, awọn ọmọ orileede yii dide soun, ti wọn si ran oun lọwọ.
O wa ni ẹbun toun fun baba naa koun naa fi lọ ra ounjẹ
sile lati maa jẹun, nitori bi ounjẹ ba kuro
ninu iṣẹ, iṣẹ ti buse. Ninu ọrọ Baba Lẹgba, o dupẹ lọwọ Iya Saidi onirọba
fun iranwọ to ṣe foun, eyi to sọ pe o jọ oun loju.
Ko to to akoko yii, ni obinrin naa ti kọkọ mu ẹbun ẹgbẹrun
lọna ọgọrun- un naira fun Kasnaty lati fi ẹmi imoore ẹ han ṣugbon tiyẹn da a pada
fun.
No comments:
Post a Comment