Gẹgẹ bi ọrọ ti Ọgbẹni Adedoyin Ọlanrewaju, to jẹ ọga agba
fijilante nipinlẹ Ogun, sọ jade lo ti ṣalaye pe lọjọ Aiku, Sannde,lakooko ti
konile-o-gbele n lọ lọwọ ni wọn mu ọkunrin naa.
Ọkan lara awọn ọmọọṣẹ fijilante, Alimi Sodik, to wa lara
awọn to n sọ agbegbe Kutọ, niluu Abẹokuta, fun ti igbele korona fairọs ni wọn
ri Aminu atọrẹ ẹ, ni nnkan bii aago mọkanla kọja iṣẹju mejila ọjọ naa.
Wọn ni ibi tawọn eeyan naa ti n rin regberegbe pẹlu apo
kan lọwọ lawọn ti fura si wọn, bawọn ṣi ṣe dawọn duro ni ẹnikeji ẹ ti sa lọ,
eyi gan-an lo jẹ ki ara fun wọn tawọn si mu Aminu.
O ṣalaye pe wọn lawọn beeere lọwọ ẹ pe ki lo wa ninu apo
to gbe dani, ṣe wọn lo n kalolo, to sọ pe oun loun ni ẹru to wa nibẹ, lawọn ba
ni ko tu u, bo ṣe di pe oriṣiriṣi irun lo wa nibẹ.
Ọga fijilante ọhun lawọn
beeere lọwọ ẹ ibi to ti ri awọn irun naa, o ni irun obinrin naa ati pe ṣe
lawọn maa n sa lori akitan tawọn si tun maa n ra lọdọ awọn to n ṣe irun lọpọ
igba.
Aminu tun jẹwọ fun wọn pe Kano lawọn maa n ta awọn irun
naa si ati pe kaakiri ilu lawọn maa n lọ lati waa fawọn to bẹ awọn niṣẹ, oun si
ti n bawọn ṣiṣẹ naa tipẹ.
Nigba ti wọn beeere lọwọ ẹ pe kin ni wọn maa fi irun naa ṣe,
wọn lo ni oogun owo ni.
Ni bayii, Ọga agba fijilante naa, Adededoyin Ọlanrewaju
ti sọ pe awọn ti mu afurasi naa lọ si teṣan awọn ọlọpaa to wa ni Ibara, ti
iwadii si n tẹ siwaju.
No comments:
Post a Comment