Nitori iwa aigbọran; Ijọba da sẹria fun Funkẹ Akindele ati ọkọ ẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 6 April 2020

Nitori iwa aigbọran; Ijọba da sẹria fun Funkẹ Akindele ati ọkọ ẹKo si bi gbajumọ oṣere-binrin onitiata nni Funkẹ Akindele ati ọkọ ẹ, Abdul Rasheed Bello ṣe le gbagbe arun koronafairọs laye wọn lakooko ti wọn ba da a silẹ.

Ki i ṣe pe wọn ko arun naa bi ko ṣe bi wọn ṣe fi wọn ṣe apẹẹrẹ ohun buruku nitori bi wọn ṣe huwa aigbọran tabi ta ni yoo mu mi, eyi to mu ki wọn si da a sẹria fun wọn.

Titi di akoko ta a kọ iroyin yii kayeefi si ni yoo si maa jẹ fawọn naa pe n jẹ iru nnkan bẹẹ le ṣẹlẹ sawọn,laimọ pe ko sẹni to kọja ofin lorileede yii.

Ile- ẹjọ Majisireeti to wa l’Ọgba, niluu Ekoo, ni wọn ti dajọ fawọn tọkọ-tiyawo naa lọjọ Aje, Monde, pe kawọn mejeeji ṣiṣẹ sin ilu fun ododi ọsẹ meji. Ninu idajọ ti Adajọ Yewande Aje-Afunwa  gbe kalẹ lo tun ti sọ pe wọ gbọdọ sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ẹnikọọkan wọn (N100,000).

Ninu ilakalẹ idajọ naa, wakati mẹta lojumọ ni wọn yoo fi maa ṣiṣẹ sin ilu, lati ọjọ Monde si Furaidee. Awọn adugbo mẹwaa, otọọtọ ni wọn gbọdọ lọ,  ti wọn yoo  maa da awọn eeyan lẹkọọ pataki lori bi wọn ṣe gbọdọ maa tẹle ofin ijọba  lati dena arun koronafairọs yii. 


Bẹẹ ni Adajọ naa tun paṣẹ pe ki awọn mejeeji wa ni iṣemọ fọjọ merinla gbako, lati le mọ boya arun naa wa lara wọn, ki wọn si ma ba a ko ran ẹlomi-in.

Ayẹyẹ ọjọọbi ti Funkẹ Akindele ṣe fun ọkọ ẹ, nile wọn ni AMEN ESTATE, lagbegbe Ibẹju Lekki, niluu Ekoo, ni wọn sọ pe o da wahala silẹ, nitori wọn saigbọran si ofin tijọba ipinlẹ Eko la silẹ lakooko yii lati dena arun ti wọn lo gbode yii iyẹn korona fairọs, ti wọn ko kawọn eeyan maa sunmo ara wọn, ki wọn si maa jade.
                      
Nnkan ti wọn sọ pe o dun ijọba ju ni pe latigba ti ajakale arun ọhun ti ko wahala wọlu, ti gbogbo agbaye si n wọna abayọ si aisan to n da gbogbo aye laamu, oṣere tiata yii naa wa lara awọn ti wọn n pariwo lori tẹlifiṣan  pe ki kaluku tẹle ofin ati ilana ti ijọba gbe kalẹ.

Ṣugbọn o wa jẹ oun naa lo wa lodi sofin, to ṣe afojudi si ijọba, idi niyii ti wọn fi da sẹria fun –un.

Funkẹ Akindele, ti tọrọ idariji o, o ni oun ko mọ ọn mọ ko awọn eeyan jọ lati ṣayẹyẹ fi lu ofin ijọba. O ni “Mo fẹ fi akoko yii tọrọ aforiji, bẹẹ ni mo fẹ fi da gbogbo araye loju pe, a ko mọ ọn mọ ṣe e o, aṣiṣe wa ni bi a ṣe gbe fidio yẹn sori ẹrọ ayelukara.  Mo fẹ fi da gbogbo araye loju pe mo duro sinsin pẹlu ijọba lori igbogunti ajakalẹ arun COVID 19 to gba igboro kan yii, bẹẹ ni mo ṣetan lati maa tẹle gbogbo ohun ti mo ba sọ, ilu Naijiria ko ni i bajẹ o.”
No comments:

Post a Comment

Pages