Ọmọọba Adeleke
Adekọya, ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bi ọba tuntun ni Oke
Agbo, Ijebu Igbo, ti rọ gbogbo awọn araalu ẹ atawọn eeyan ipinlẹ Ogun, lati ma
ṣe kanju ju ijọba lọ lori igbesẹ konile-gbele ti wọn ni ki gbogbo wọn wa.
nitori arun koronafairọs ti wọn lo n tan kaakiri yii.
Gẹgẹ bi atẹjade ti ọkunrin naa fi
sita, lo ti sọ pe ki gbogbo awọn eeyan fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati le tete dẹkun
arun naa, ko ma di nnkan ti apa ko nii le ka lọjọ iwaju.
O wa gba awọn eeyan niyanju lati ma
ṣe awọn nnkan ti ajọ ilera lagbaye la kalẹ lati maa ṣe, nipa fifọwọ wa
loorekoore pẹlu ọṣẹ ati omi to mọ, ki wọn si maa bo imu wọn, nitori awọn idọti
to le ikọ, tabi sinsin, ki wọn si sọra fun pe wọn n bọ awọn eeyan lọwọ lakooko
yii.
Bẹẹ lo tun
gbawọn niyanju ki gbogbo awọn eeyan duro sile titi di akoko tijọba fun wọn da,
o ni gbogbo igbesẹ tijọba n gbe fun anfaani awọn araalu naa, nitori ko si nnkan
to dara to ki gbogbo eeyan wa ni alaafia.
O tun wa
lo anfaani naa lati ke si awọn ẹlẹyinju aanu lati dide iranwọ sijọba lati jọ
gbogun ti arun naa, ki wọn ṣi ṣe nnkan to ba ti ọkan wọn wa lati fi ran eto ẹka
ilera lọwọ.
O gbadura pe laipẹ yii ni arun naa yoo poora lorileede
yii ati ni gbogbo agbaye, nitori nnkan to n ṣẹlẹ lakooko yii, arun gbogbo aye
ni.
No comments:
Post a Comment