Awọn to ku-diẹ kaato fun ni ounjẹ tipinlẹ Ogun fẹẹ pin wa fun, ki i ṣe ẹgbẹẹgbẹ. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 5 April 2020

Awọn to ku-diẹ kaato fun ni ounjẹ tipinlẹ Ogun fẹẹ pin wa fun, ki i ṣe ẹgbẹẹgbẹ.




Ijọba ipinlẹ Ogun ti sọ di mi mọ pe awọn ounjẹ tawọn fẹẹ pin fun ti konile-o-gbele to n lọ lọwọ nipinlẹ naa, fun ti koronafairọs ki i ṣe fun ẹlẹgbẹjẹgbẹ bi ko ṣe fawọn mẹkunnu, to ku-diẹ- kaato fun lawujọ.

Ninu atẹjade kan ti Kunle Ṣomọrin, akọwe fun Gomina Dapọ Abiọdun fi sita lo ti pakiyesi sawọn oriṣiriṣi aworan fidio tawọn ẹgbẹ idagbasoke agbegbe kan gbe jade lori ounjẹ ti wọn fẹẹ fawọn araalu.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni awọn fidio jẹ eyi to ba ni lọkanjẹ lakooko taa wa yii, eyi to ni wọn ti fẹ kọwọ oṣelu bọ. O ni nitori kawọn eeyan ba ma ṣe ṣe iyemeji lo jẹ kijọba pese awọn nnkan wonyii bii irẹsi kilomita marun-un, ẹwa kilomita marun-un, gaari kilomita marun-un iyọ, maggi isebẹ, ororo, tomaati oni pepa pẹlu ami idanimọ ipinlẹ Ogun ti wọn fi se baagi ẹ.

O sọ pe  awọn to wa nile kọọkan lo wa fun ki i ṣe fun adugbo tabi ẹgbẹ idagbasoke. O fi kun ọrọ ẹ pe awọn ile ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta, to ku diẹ kaato fun
ti wọn to milọnu mẹta ni yoo ni ipin ninu ẹ. Eyi to ni pinpin awọn nnkan ọhun ti igba akọkọ ti bẹrẹ, tawọn ile bi ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kaakiri ijọba ibilẹ Ogun yoo ti janfaani.

Atẹjade naa tun sọ pe nitori ki igbele ọhun ko ma ni awọn eeyan lara ju lawọn ṣe sọ pe lati alẹ Furaidee titi di aarọ Tusidee, ni igbele yii yoo fi waye, tawọn eeyan yoo si jade lati aago meje aarọ si meji ọsan, ọjọ naa lati jẹ kawọn eeyan ni anfaani lati ra ounjẹ sile. Bẹẹ lawọn yoo si ma faye silẹ bẹẹ titi ọjọ mẹrinla naa yoo fi pe. Ijọba lawọn ko le ti ipinlẹ Ogun pa fọjọ mẹrinla, wahala nla ni.

Ootọ ọrọ to wa nibẹ ni pe ijọba nikan ko le pese nnkan tawọn eeyan ilu n fẹẹ.O ni nitori ki nnkan ti wọn n pin naa le de awọn ibi ti wọn n fẹ lawọn ṣe gbe awọn igbimọ kan dide lawọn ijọba ibilẹ nibi tawọn idagbasoke wa ninu wọn, awọn ti wọn tun wa nibẹ ni awọn olori ẹsin, iyalọja ati babalọja atawọn mii in.

Gomina Dapọ Abiọdun, wa rọ awọn araalu ki wọn ma ṣe gba awọn fidio ti wọn ṣafihan ẹ lori ẹrọ ayelujara gbọ, o ni awọn ti wọn fẹ ma sọ gbogbo nnkan di ti oṣelu lo wa nibẹ. O ni akoko tawọn wa yii, awọb araalu gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu wọn lati bori awọn ọta, mi mu ayedẹrun lo ni o jẹ ijọba oun logun

No comments:

Post a Comment

Pages