Iku ọga ọlọpaa Ibara da wahala silẹ l`Abẹokuta, wọn ni ko lọwọ eegun ninu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 5 April 2020

Iku ọga ọlọpaa Ibara da wahala silẹ l`Abẹokuta, wọn ni ko lọwọ eegun ninu


Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ awọn ọlọpaa ni Eleweran, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ti gbe atẹjade kan sita pe ko si ootọ ọrọ kankan ninu ahesọ ọrọ tawọn kan n sọ nigboro pe iku to pa oju ọga ọlọpaa iyẹn DPO, ti Ibara, Ọgbẹni  Ṣẹgun Dada de, ko ṣe lẹyin ti eleegun ti wọn mu. 
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn ni isọkusọ gbaa lawọn eeyan naa n sọ, nitori lati bi oṣu kan sẹyin ni DPO naa ti wa ninu aisan, ko to di pe o mu ẹmi ẹ lọ, lọjọ Ẹti, Furaide, to kọja yii.

Latigba ti ọkunrin naa ti ku loriṣiriṣi ahesọ ọrọ ti gba igboro paapaa laduugbo Ijẹja, nibi tawọn ọlọpaa ti mu eegun naa fun pe ko pa ofin ijọba mọ lori mọ- sun- mọ- ara- ẹni ti wọn gbe jade nitori arun koronafairọs to gbode.

Ohun ti wọn lawọn eeyan ọhun sọ ni pe afojudi lo pa ọlọpaa nitori eegun alagbara lo foju di. Awọn kan ti wọn ko mọ bọrọ ṣe ṣẹlẹ tun  sọ debi pe ibi kan wa ti wọn n pe ni Idi-Isin lagbegbe naa, ti wọn pe ni ojubọ eegun naa, wọn ni ọga ọlọpaa yii debẹ, to si da a ru.

Wọn ni ati pe bawọn ọlọpaa ṣe bọ aṣọ ẹku lọrun eegun naa, ti wọn si jẹ ki wọn mọ ẹni to wa nibẹ gan-an lo jẹ ko binu. Ṣugbọn atẹjade awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ pe ọkunrin DPO Dada naa ko si lara awọn to lọ mu eegun naa.

Ati pe ibi ti ọkunrin naa ti n gba itọju lo wa lakooko ti wọn fi lọ mu eegun yii, ko si nibẹ rara. Wọn ni ẹnikẹni to ba mọ ọga ọlọpaa yii nigba to wa laye mọ pe o jẹ oniwa irẹlẹ, ti ko ni aapọn, to si tun ni iwa irẹlẹ, idi niyii ti iku ẹ fi n kawọn eeyan lara. Ẹni tawọn ọlọpaa ko le gbagbe ni.

Awọn ọlọpaa tun sọ pe ohun to mu kawọn mu awọn Pasitọ atawọn aafaa lori pe wọn ludi ofin, ko si nnkan to da wọn duro lati maa mu eegun to ba rufin.

Wọn wa pari ọrọ wọn pe pẹlu gbogbo ahesọ ti wọn n gbe kaakiri yii ko le dawọn ọlọpaa duro lati ma ṣiṣẹ wọn.


No comments:

Post a Comment

Pages