Ọga agba fun ileeṣẹ to n ri si abo araalu, iyẹn Siifu, nipinlẹ
Ogun, Alaaji Ahmed Abọdunrin, ti rọ awọn araalu pe ibi ti wọn ba ti ri i pe awọn
alaabo ti wọn wa nigboro jakejado ipinlẹ naa fun ti konile-o-gbele to n lọ lọwọ
ba ti na awọn kọlọransi, ki wọn tete jẹ kawọn n gbọ, nitori wọn ko fun wọn laṣẹ
bẹẹ.
O sọrọ yii lakooko to fọrọwerọ pẹlu akọroyin BO ṢE RI ni ọfiisi
ẹ nipa igbaradi wọn lori konile-o- gbele to ti bẹrẹ bayii nitori arun
koronafairọs to gbode. O ni kaka bẹẹ awọn ti la awọn ọna to dara ju ki wọn na
eeyan lọ silẹ fawọn tọwọ ba tẹ.
Ọkunrin naa sọ pe ko to di pe eto naa bẹrẹ lawọn ti fi
iriri wọn lati ma jẹ kawọn eeyan wọle lati awọn ipinlẹ to mule tipinlẹ Ogun bẹẹ
lawọn ko si jẹ ki wọn jade ṣe igbaradi wọn,
ati le koju awọn iṣoro kekekee nigba ti igbele ọhun ba bẹrẹ.
Lara awọn nnkan tawọn foju ri ni pe awọn eeyan ko tẹle ofin
tijọba la kalẹ, ko ti i mọ wọn lara daadaa. O ni awọn ṣi n rawọn eeyan to fẹẹ wọle
bẹẹ lawọn to fẹẹ kọja si Eko, Ibadan ati Ondo, o ni teeyan ba tapa si ofin o yẹ kawọn mu wọn.
Abọdun ṣalaye pe’ Ṣe ẹ ri igbelewọn ka jinna si ara wa,
ko le gba ka mu eeyan, ka ti i mọle, ẹni ti ẹ fẹẹ ti mọle gan-an,ẹ o mọ boya arun
kan wa lara ẹ. A ti wa dọgbọn kan ta a pe ni itimọle ti ko ni kọkọrọ. Ẹni ta a
ba ni ko pada sibi to ti n bọ, to ba ba wa lagidi, awa o nii ba a ja, a o mu pẹlu mọto tabi kẹkẹ ẹ to wa, a o fi
sibi to jẹ ibi gbangba, o le jẹ papa ti wọn ti n ṣere, ti wọn yoo fi jinna si
ara wọn, pe ki wọn jokoo sibẹ. Nigba ti yoo ba fi lo wakati meji si mẹta, a mọ
pe oun lo maa bẹbẹ pe, ta a ba fẹ koun lọ
sibi toun lọ, ki wọn jẹ koun pada sile’.
O ni ko ti ye awọn eeyan daadaa, ikeji ni pe ẹni to ba
tapa si ofin, ko sibi tawọn fẹ ti wọn mọ.
Awọn si ti ri ọgbọn da, to kọja nina. Pẹlu gbogbo eleyii, o ni yoo jẹ ki
ofin konile-o-gbele rinlẹ, ko nii nira rara..
Ọga agba Siifu tun fi kun ọrọ ẹ pe “A ti ṣe idanilẹkọọ
fun ọọdunrun oṣiṣẹ wa, lati kọ wọn bi wọn yoo ṣe ṣiṣẹ, a tun da wọn lẹkọọ lori
idabobo ara wọn, nitori ẹni to ba wa ni alaafia ni yoo le ṣiṣẹ idabobo fun
eeyan, tawọn naa ba ti wa ni wahala, ko si bi wọn ṣe le fẹẹ ṣe, a ṣe idanilẹkọọ
lori abo tara wọn.
Fun akọkọ, awọn oṣiṣẹ bii ọọdunrun ti gba idanilẹkọọ, tawọn yẹn ba ṣiṣẹ tan, nitori iṣẹ yii ki i ṣe mo wa laaarọ, mo fẹ lọ sile, iṣe aṣeyipo ni. Awọn kan yoo wa ni aarọ, awọn kan ni alẹ. Nitori awọn kọlọransi ti wọn le maa roo pe bi wọn ko ba jẹ kawọn jade ni aarọ, awọn a jade ni alẹ”.
O ni bi ọsẹ akọkọ ba lọ tan, awọn tun fẹẹ bẹrẹ awọn igba
oṣiṣẹ mii- in, lati fun wọn ni idanilẹkọọ,.ti ko fi ni wọ awọn iṣi akọkọ lọrun.
Gbogbo wọn lapapọ, lo ni wọn jẹ ẹẹdẹgbẹta
oṣiṣẹ tawọn fẹẹ lo.
O wa ṣe ikilọ pe kawọn ọdaran ma ṣe lo akoko yii pe ko
sibi ti wọn ti wọn mọ, ti wọn ba daran ṣiṣẹ ibi, ki wọn maa wa fi daran kaakiri,
o ni iiyẹn a le koko, nitori awọn yoo kọkọ fi pankẹrẹ fin ara onitọhun, lati ma
jẹ ki aisan to wa lara ẹ ran ẹlomin in, awọn yoo ti mọle. O ni oun mọ pe ijọba
apapọ yoo ti maa ṣeto, ibi ti wọn maa fi awọn ọdaran si, ti arun to wa nita, ko
nii ran wọn.
No comments:
Post a Comment