Nitori koronafairọs; Wọn sun ayẹyẹ ifilọlẹ ajọ Yẹmisi Mercy siwaju - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 2 April 2020

Nitori koronafairọs; Wọn sun ayẹyẹ ifilọlẹ ajọ Yẹmisi Mercy siwaju


Nitori ofin konile-gbele tijọba fi sita fun arun ti koronafairọs to gbode, wọn ti sun ayẹyẹ ifilọlẹ kan ti wọn pe ni Yẹmisi Mercy Foundation to yẹ ko waye lọjọ kọkanla, oṣu yii, siwaju.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Ọgbẹni Adeniyi Adeloye, oluranlọwọ pataki fun Pasitọ Sẹyẹ Sẹnfuye, oludasilẹ ijọ ile iṣura, ‘Treasure House of God’ fi sita lo ti sọ pe awọn yoo kede ọjọ tuntun ti wọn yoo ṣe laipẹ.

O ṣalaye pe ajọ ti wọn fẹẹ ṣe ifilọlẹ ẹ yii ni wọn fi sọri Oloogbe Pasitọ Arabinrin Oluwayemisi Senfuye - George, ẹni to jade laye lọdun to kọja. O fi kun ọrọ ẹ pe wọn ṣagbekalẹ ajọ naa lati maa ran awọn opo, alainiya atawọn to ku diẹ kaato lawujọ lọwọ.

Ṣọọṣi ọhun, Treasure House of God,  to wa ni Quarry, niluu Abẹokuta, ni ayẹyẹ naa yoo ti waye lọjọ tuntun ti wọn ba ṣẹṣẹ mu.

No comments:

Post a Comment

Pages