Alaaji Onarebu Kelani Lukman Taiwo topo mo so Kelat, oludije fun ipo alaga ijoba ibile Abeokuta South labe egbe oselu APC ti so pe gbogbo erongba oun toun ba di alaga ijoba ibile naa ni lati je ko tun dotun ju bo se wa yii lo ati lati je ki o tun ni idagbasoke si.
Okunrin yii
naa soro lakooko to n ba oniroyin wa soro, o ni lakoko naa oun ki Gomina Dapo
Abiodun ku oriire, bo tun se jawe olubori nibi ejo kotemilorun lose to koja. O
ni apeere pe Olorun lo mo on mo yan lati wa sise nipinle Ogun.
Bee lo so pe
ipo alaga ijoba ibile Abeokuta South toun jade yii, ki i se fun ere rara, bi ko
se lati tesiwaju ninu ohun rere tawon to ti se tele ati lati safikun agbara ati
imo ti Olorun foun lati le je ko gbooru si.
Kelat, eni
to ti ni imo oselu lati nnkan bi ogbon odun seyin tun fi kun un pe awon eto marun un lo je pataki toun ti
la sile, bi won ba foun laye lati depo naa.
Awon eto naa
ni ogbin, eto eko to dara,ilera, riro awon odo lagbara ati idagbasoke to ni se
pelu mimu ayederun fawon to wa nijoba ibile naa.
O ni ohun to
dara ni ki adugbo ati agbegbe dun un wo, idi niyii toun yoo fi sagbara lori
awon imayederun, bee lo ni eto tun fawon obinrin nipa di da won lokoowo, ati ri
ro won lagbara lori ona ati je won.
Kelat tun salaye pe bi gbogbo wa se mo pe ijoba to wa lode yii sakitiyan won nipa oselu, nitori e, loun naa yoo se eko lokunkundun lawon ileeewe alakobere ati ti girama to wa nijoba ibile naa. O si da oun loju pe ipo asaaju ti Abeokuta wa lagbaaye nipa eto eko naa ni won yoo maa wa.
O wa ro awon
agba egbe oselu APC nijoba ibile naa lati foun ni tikeeti, koun le jade labe
asia agbe naa ninu ibo ijoba ibile to n bo, o wa seleri pe oun ko nii doju ti
won lagbara Olorun.
No comments:
Post a Comment