Oginni ni ki Dapo Abiodun wọdi Arabambi daadaa lori lẹta to kọ si Amosun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday, 16 November 2019

Oginni ni ki Dapo Abiodun wọdi Arabambi daadaa lori lẹta to kọ si Amosun


 
Kọmureedi Sunday Oinni ti egbe oselu lebọ nipinle Ogun ti ke si Gomina Dapọ Abiọdun lati ṣe iwadii lori leta ti Abayọmi Arabambi kọ si Ibikunle Amosun gomina tele nipinlẹ naa, nibi to ti beere owo lọwọ ẹ.

Gẹgẹ bi atẹjade to fi sita lo ti ni Arabambi ati oludije gomina labẹ egbe oselu lebọ, Modupe Sanyaolu ti beere fun milionu lona ogun naira lowo Ibikunle Amosun fun owo gba- ma- binu ti wọn lo fi pẹjo lakooko ti igbẹjo gomina n lọ lowo, ninu eyi ti Dapo Abiodun ti jawe olubori.

Bo tile je pe Arabambi ti ko jale pe oun ko mo nipa leta naa sugbon Oginni so pe ko si nnkan to le sele to mu ki Abiodun gba lati se ipade po pelu Arabambi atawọn to ko lo sodi to pe ni omo egbe IPAC.
Okunrin naa so pe ibeere nla tawon eeyan ipinle Ogun  nipe pelu gbogbo iwa ti Arabambi hu fun ibaniloruko je gomina, se o ye pe iru ẹ ni gomina ipinle Ogun yoo maa jokoo papo se ipade pọ.
O ni edun okan lo je pelu bi Arabambi se jewo fun gbogbo agbaye pe Gomina tele nipinle Ogun, Ibikunle Amosun ati Akinlade gba oun lati sise ibi fun Dapo Abiodun lakooko ibo ati igbejo naa.
Oginni so po"I Ninu arigbamu leta meji otooto ni Arabambi ti ko nitiju yii ti beere fun milionu lona ogun naira lowo Amosun fun ise ibaje.

 "Leta mejeeji fun ise ibi ti won gba ti won ti beere owo e ni Arabambi ati oludije e fun ipo gomina Dupe Sanyaolu fowo si..

Oginni ni gbogbo igba yii lawon tawon je lebo lati igun keji sise fun Gomina Dapo Abiodun tawon duro tii gboingboin gbogbo igba to fi wa nileejo.

O wa beere lowo  Dapo Abiodun pe milionu marun un to fun Arabambi, se owo gba- ma- binu fun ise ibi to ge lati tako, eyi to ni Amosun ati Akinlade ran okunrin yii ni a bi ewo?

O ni awon wa lo akoko yii lati ro Dapo Abiodun lati se iwadii lori awon leta naa pelu awon to daruko won sinu e. Bee lawon tun pe gege bi olori alaabo ipinle yii lati fi ife han lori awon leta naa atawon  nnkan to wa nibe.

No comments:

Post a Comment

Pages