Egbe apapo
oloselu nipinle Ogun ti so pe oro ti Arabambi so pe oun da awon kan duro ninu
egbe oselu naa dabi eni to n se tiata, to si mo nipa awada, nitori oun gan-an
naa mo pe ala ti ko le se ni.
Ninu atejade
tawon alaga egbe apapo oloselu naa fi sita, eyi ti Ogbeni Olaposi Sunday,
Moshood Adesina ati Mosuro Adebayo fowo si lojoruu, Wesidee, ose yii ni won ti
so pe gbogbo awon asaaju egbe oselu ni won fi aidunnu won han lori bi won ni
Arabambi se n gbero, ko lese nile.
Ati pe okunrin
yii gan-an funra e lawon igun mejeeji to wa legbe oselu Lebo to ti jade wa ti
daa duro ninu egbe won. Ti won si tun ti kilo fun pe ko ye pe ara e ni alaga
egbe IPAC mo.
Bakan naa ni a
gbo pe Gomina Dapo Abiodun, ti we ara e mo ninu wahala to n sele ninu egbe IPAC
pe oun ko mo nnkankan nipa e.
Ati pe ko sigba
kankan ti Gomina pase fun Arabambi lati da awon kan duro ninu egbe apapo oselu
nipinle naa. Bee lo si ti kilo fun won pe ki won ma da toun si oro to wa nile,
nitori gbogbo igbese ti Arabambi gbe oun ko mo nipa e.
Ni bayii, awon apapo egbe oselu nipinle Ogun, IPAC ti wa
so pe pelu bi nnkan se n loo yii, awon ti setan lati so Arabambi di eni ileele
ti ko niyi mo ati pe awon ko figba kankan kaa kun gege bi omo egbe won mo.
No comments:
Post a Comment