Nitori Arabanbi apapo egbe oselu binu si Dapo Abiodun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 6 November 2019

Nitori Arabanbi apapo egbe oselu binu si Dapo Abiodun



Apapo egbe oselu nipinle Ogun, IPAC, ti fi aidunnu won han lori ipade kan ti won ni Abayomi Arabambi to je alaga won ati Gomina Dapo Abiodun se papo.

Gege bi won se wi ninu ipade oniroyin kan ti won se ni ale ojo Isegun, Tusidee, ni won ti so pe abuku nla ni fun Gominna lati gba okunrin yii laye lati jo jokoo papo pelu gbogbo nnkan to se lakooko ibo to waye
ati nigba ti won pari ibo.

Sunday Olaposi Oginni, to koko soro nibi ipade awon oniroyin naa ni o ti so pe o ba awon lokan je nigba tawon gbo pe Arabanbi lo ki Gomina ati pe ko ye ki Gomina gbaa laaye, lati jo soro papo.

O salaye pe gbogbo ogbon jibiti ti Arabanbi maa n lo lawon mo ati pe ko si omo egbe IPAC kankan ti won je ojulowo to wa laarin awon to ko lo pade Gomina Abiodun.

O ni iyalenu lo je pe Arabanbi to ni Dapo Abiodun ko koju osuwon lati di gomina, to gbe Gomina lo sile-ejo nipa ibo gomina to waye, to ni ko niwe eri, to ledi apo po mo Ibikunle Amosun, ni Abiodun wa fun laaye
lati ba soro, o ni abuku nla, to si tun seleya gomina funra e.

Oginni ni gbogbo awon egbe oselu APC lawon ti foro naa lo pe bi Gomina ba le se ipade po pelu okunrin abanije yii a je pe Dapo Abiodun yeye ara e, tinu awon araalu ko si le dun si.

O tun salaye pe bi atunse ko ba tete waye a je pe Gomina Abiodun fee maa sise po pelu awon adigunjale oloselu.

Oginni  ni gbogbo awon to wa nibi ipade oniroyin naa ni ojulowo omo apapo egbe oselu nipinle naa. O ni Arabambi funra e gan an pe oun pe wa pelu oun sugbon oun yari pe oun ko se nitori o lodi si ofin egbe.

Loro kan nnkan to lawon so ni pe ipade ti Gomina se pelu Arabambi ko lese nile, kangaru ni, awon tawon je ojulowo omo egbe apapo oselu ko mo nnkankan nipa e.

Ninu oro Ogbeni Moshood Adesina, to je alaga egbe oselu Mega Party, to tun je igbakeji alaga apapo egbe oselu nipinle Ogun naa so ni tie pe ko ye kawon tun ma gba igba bi eni gba oti, o ni oro ti Sunday Oginni, to je akowe egbe oselu Labour so lawon duro le lori.

O kan fikun pe abuku ati egbin nla ni awon ka ipade naa si, nitori pelu bi Arabambi se gbindanwo lati ma je ki Gomina de ipo, to tun so pe ko kun oju osuwon, to tun gbee lo sile ejo, ni Gomina wa farabale jokoo ti lati se ipade po. O ni ki i se ipade apapo egbe ni won se o, won kan lo lu gomina ni jibiti gege bo se maa n se ni.

Bakan naa ni gbogbo awon to tun soro naa fi aidunnu won han si ipade naa, won si ni ko ye ko je pe Gomina ni yoo se iru e sawon.





No comments:

Post a Comment

Pages