Lati le mu adinku ba
bi iwa ajinigbe, aini eto abo to peye ati wahala laarin awon agbe atawon
Fulani, ileese alaabo siifu tipinle Ogun ti sagbekale awon ti yoo maa doju ija
ko awon nnkan wonyii, ti alaafia yoo si de ba gbogbo awon olugbe ipinle naa.
Lojobo. Tosidee
ni eto naa waye logba awon siifu tuntun,
to wa ni Kobape, niluu Abeokuta. NIgba to n soro nibi eto naa,Ogbeni Hammed
Abodunrin, to je oga agba fajo alaabo naa nipinle Ogun, so pe pataki ni eto
aabo je fawon araalu ati pe ise to wa laye to si wa laaye ni.
O ni idi e lo se se Pataki
fun gbogbo awon to ba je alaabo lati wa ona bi eto abo to peye yoo se wa fun
gbogbo mutumuwa, lati da emi ati dukia si.
O so pe aini eto abo
to peye lo mu ko je pea won igbo wa, to ye ko wulo lati maa pese awon ohun
amulo fun wa ti wa di ibi tawon odaran n sapamo si, ti ko si bojumo
Abodunrin tun fikun
oro e pe gbogbo awon nnkan wonyii lawon
ileese alaabo ri ti won fi gbe igbese lati da awon ti yoo maa awon alaabo won
lati maa ri si awon inu igbo ijoba naa.
O so pe’“ Awon ta a
sese da sile yii won ko wa fun ere rara, ojuse won si ni lati pese aabo to peye
fawon Agbe, Fulani,atawon eran to wa ninu igbo, pelu awujo.
O so pelu idaniloju pe
gbogbo awon to wa nibe ni won ti gba idanilekoo to ye koro lori ona lati samojuto awon nnkan to nii se pelu okoowo
agbe yala aladaani tabi tijoba, to si da oun loju pe won yoo maa sise won bo se
to ati bo se ye.
Oga agba siifu tun
salaye pe oga agba patapata fun ileese siifu, Mohammadu Abdullahi Gana, maa n
gba awon tawon je omo labe e niyanju lati maa sise won bo se to gege bi won se
gba a.
Ki won si maa ri pe won
mu ise naa lokunkundun.
O wa salaye idi ti won
fi lo okada fun eto tuntun naa, o ni ki i
se fun ako rara, ara
eronja ise awon ni ninu igbo nigba ti won ba fee maa kaakiri, moto si le ma de
be.
O ni awon okada atawon
eeyan oun to gba idanilekoo naa da oun loju pe ko si bi oke naa se le gun to ti
won ko ni fi gun-un layo ati alaafia.
Abodunrin ni nibi to
le de, awon tun mo pe awon ibikan tun wa ti okada ko le gba, idi niyii tawon
tun fi ni esin yoo wulo lawon ibe.
Ati pe igbakigba ni
epo le tan ninu okada sugbon esin kii lo epo.
Ninu oro ti Gomina
ipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun, ran sibi eto naa, eyi ti igbakeji e, Noimot
Salako Oyedele je nibe, lo ti so pe isakoso oun n sise pelu igbimo eyawo feto
aabo gidi, lati le pese awon ohun amulo
fun abo nipinle naa.
O ni ogorun un moto
ati okada igba lawon ti ra lati fi
gbogun ti iwa odaran nipinle naa.O ni igbese tuntun lawon siifu gbe pelu bi won
se sagbekale awon ikon aa.
O wa so pe o ye ki won
pese awon ohun ibanisoro sawon moto atawon nnkan ti wo n lo lati le je ki ise
naa le maa ya, fun ipese aabo to peye.
Lojo naa ni won tun
seye fawon igba osise won ti won sese ni igbega lati ibi kan bo sikeji. Gomina
Dapo Abiodun wa ki awon ti won gba igbega naa ku oriire, o si gba won niyanju
lati sise won bo se to lawujo.
No comments:
Post a Comment