Single link Magazine fun Baroka lawoodu nla. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 1 October 2019

Single link Magazine fun Baroka lawoodu nla.Fun ipa pataki to maa n ko ninu fiimu ati ere ori itage gege bi eni ti Olorun fun lebun nipa ise naa, ileese iwe iroyin oloyinbo kan Single Link Magazine, ti won tun je alakoso ileese Doyin Asiru Concept ti fun gbajumo agba osere onitita nni, Rasak Oyadiran, topo mo si Baroka.

Nibi ayeye to waye lojo Abameta, Satide, to koja yii, lawon osere bii Laide Bakare, Gbenga Adeyinka, Alesh Onigbale,Friday Elegbede, Salawa Abeni atawon mii in naa tun gba awoodu lori ipa tawon naa ko ninu ise ti won yan laayo.

Gege bi a se gbo, ileese Adedoyin yii ti wa lati nnkan bii odun merindinlogbon seyin. Obinrin naa si ti wa lenu e tipe ninu ka gbe asa laruge, to si ti kopa pataki ninu e nile yii ati ti  oke okun.

Nibi ayeye won ti odun yii ni won ti won Baroka ni awoodu lati fi je ko mo pe awon eeyan n gbadun e, ti won si fi se oun iwuri fun un.

Ninu oro Agba osere yii nibi ayeye naa, lo ti dupe lowo awon to se agbateru eto naa, o ni iyen yoo je koun tubo mura sise naa ati pe kekere si lawon eeyan n ri, nitori ebun naa si wa digbidigbi.

No comments:

Post a Comment

Pages