Egbe Roodu ipinle Ogun ti wa ni isokan, ko si wahala kankan mo laarin wa- Efele - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 30 September 2019

Egbe Roodu ipinle Ogun ti wa ni isokan, ko si wahala kankan mo laarin wa- Efele




Oluomo Akibu Titilayo, topo awon eeyan mo si Efele, to je alaga igbimo alamojuto fun egbe Road Transport Employer Association of Nigeria, RTEAN nipinle Ogun, ti so pe ko si wahala kankan mo ninu egbe naa ati pe awon ti wa nisokan.
O soro yii lakooko to n se ipade po pelu oniroyin wa leyin to pari ipade pelu awon igbimo alamojuto ti won sese yan nipinle Ogun, eyi to waye ni ofiisi egbe naa ni Obantoko, niluu Abeokuta.
Okunrin naa wa ro gbogbo awon alaga lawon ekun won kookan lati pada sile loo se ipade po pelu awon eeyan won, ki won si ri pe won yanju gbogbo nnkan to le maa da aawo sile laarin ara won.
Bee lo tun ro won lati ma se awon omo egbe roodu nisekuse, gbogbo idagbasoke tuntun ti won fee mu ba egbe naa lo ni ki won fi to won leti, ki won si je ki won mo pe ko si iyapa mo ninu egbe naa, gbogbo won ti di okan.
O ni enikeni ninu won ko gbodo le omo egbe naa jade ninu egbe, o wa ni enikeni to ba ni ehonu, ko kowe ranse sodo awon omo igbimo alamojuto, pelu ileri pe loju ese lawon yoo sise lee lori.
Alaga egbe roodu naa ko sai tun so pe gbogbo bi nnkan ba se n lo lawon yoo je kawon omo egbe maa gbo, ko si ijoba adase loro toun. O wa ni gbogbo igba lawon yoo maa sise po pelu ijoba ki alaafia le joba.
Lori ibeere awon oniroyin pe kinni erongba egbe naa lati le je ki ilosiwaju de ba egbe naa ati lati fowosowopo pelu ijoba ipinle Ogun, OgbeniTiwalade Akingbade  to je akowe egbe naa, so pe lara erongba  awon ni pe ki ipade maa loo loorekoore, nitori inu osu kejila odun to koja lawon ti se ipade bee gbeyin.
Bee lo ni awon tun fee koko yanju gbogbo awuyewuye inu egbe naa, idi niyii ti alaga awon fi so pe eni to ba ni ikunsinu, ko ko leta ehonu, ko fi ranse, awon yoo si sise lee lori.
 O ni bo tile je nnkan tawon kan so ni pe nnkan to sele ninu egbe roodu lowo oselu ninu sugbon awon so pe ko si nnkan to jo o rara, ko sowo oselu kankan nibe.
Akowe  egbe naa tun so pe igbekale egbe naa to ti wa tele lawon si n tele, nitori opo awon agbaagba egbe naa, to fi mo awon to ti joye ri gbogbo won naa lawon jo n se po.Bee lo ni ajosepo oun atawon ijoba apapo danmoran yoo si tubo maa te siwaju ni.
Lori awon kan ti won pe ara won ni ojulowo iyen Authentic, Akingbade topo mo si Paulo Rossi tun dahun pe ko si ojulowo kankan ju awon yii lo, nitori awon nijoba ti n baa sise po tipetipe titi di akoko yii.
Ati  pe boun se wa n soro yii, gbogbo awon ti di okan,ko si iyapa mo laarin won,

No comments:

Post a Comment

Pages