So-Safe Corps fawon egberun mefa omoose won ni idanilekoo ni Ofada. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 30 September 2019

So-Safe Corps fawon egberun mefa omoose won ni idanilekoo ni Ofada.Lati le fi iriri kun iriri nipa ise eto abo niluu egbe alaabo ilu, So-Safe Corps ti n se idailekoo fawon egberun mefa awon omoose won, eyi to ti bere lati ojo Aiku, Sannde, ti yoo si wa sopin lojo kejo, osu kewaa, odun yii niluu Ofada, nipinle Ogun.

Gege bi atejade ti Ogbeni Moruf Kolawole Yusuf, to je agbenuso fun ileese naa se, o ni ohun ti idanilekoo naa da le lori ni igbese lori idabobo agbegbe.

Okunrin naa so pe onipele ipele ni idanilekoo naa, lara e ni eyi to so pe o ti waye lojo kejilelogun osu yii, di Ojobo, Tosidee, ojo kerindinlogbon. Bee lo ni okan yoo tun bere lola, Tusidee, ojo kin in ni osu kewaa titi di Tosidee, ojo keta osu, nigba to ni pambambari e yoo bere lojo kefa, osu kewaa, titi di ojo kejo osu, nibi ti asekagba yoo ti waye.

Okunrin naa tun so pe gbogbo awon eka won gbogbo ni awon osise won yii ti wa n gba idanilekoo  ni ibudo ti won ti n se iyen Old Intercontinental Training School, Ofada.

Moruf Yusuf tun fi kun oro e pe ileese awon olopaa ni won ti n wa fun won ni idanilekoo naa lori ona ti won fi le koju awon isoro bii ajinigbe atawon odaran yooku lona igbalode.

Ojo kejo osu kewa ni won yoo pari idanilekoo naa nibi ti won yoo ti fawon olukopa ni iwe eri. Oga agba fun ileese abo So-Safe Corps, Soji Ganzallo, ti wa seleri pe iyato gedegbe ni yoo waye fawon omoose naa ati ipinle Ogun nipa eto abo gege bawon se gbaa bii ise.


No comments:

Post a Comment

Pages