Oloye Waheed Olatunde Yusuf, topo mo si Olumo Records to je Baale tuntun ti won sese fi je ni Orile Ilugun, nijoba ibile onidagbasoke Orile-Ilugun, nipinle Ogun, ti so pe ilu naa ti letoo lati maa je Oba dipo Baale ti won si n je bayii, o ro ijoba ipinle naa lati tete fawon ni igbega ki won sig be igbese.
O soro yii
lakooko to n si ile tuntun to sese ko siluu naa, eyi to dabi afin si Orile Ilugun, eyi to waye lojo Abameta,
Satide, ibi tawon eeyan pataki awon Oba, Baale atawon oloye to yi ilu naa ka
ati ni Abeokuta.
Nigba to n
ba oniroyin wa soro leyin ti won pari ayeye naa, Baale tuntun naa so pe ni o da oun loju pe laipe yii niluu naa yoo
deni to ni oba dipo Baale ti won je bayii.
O so pe
lodun 2015 ni won foun je Baale ilu naa leyin teni to ti wa nibe ti ku, o ni
apapo omo ilu atawon Ologboni ni won foun je oye naa nigba naa.
O ni bi won
se foun je oye naa tan ni won mu oun lo ba Oba Adedapo Tejuoso, Osile ti
Oke-Ona lati fase si, latigba naa loun ti wa nipo naa.
Nigba to n
so nigba bi won se fi won je Baale ni Ilugun, Olumo so pe’ Ipo lawujo ni akoko,
leyin naa onitohun gbodo dara po mo Ogboni.
O so pe kii
se pe idile kan pato lo n je oye naa, bi ko se ki onitohun niwa rere, ko
gbajumo, ko kawe, ko si ma je odaran lawujo, awon nnkan to so pe awon omo ilu
maa n wo mo won niyen.
Oloye Waidi
tun salaye pe nitori iwa rere toun se lawon Ogboni se koko foun je Sagua ko to di
pe oun wa gba igbega sipo Baale toun je yii.
O ni ile
toun si lojo naa kii se pe oun kan si lasan bi ko se lati maa gbe ibe, nitori
ilu Baba oun ni, oun si fee je ki idagbasoke deba ilu naa, nitori gbogbo awon
omo ilu naa ti won wa loke okun loun yoo
ri pe won wa si ilu lati wag be nnkan rere se, ti ilu naa yoo fi bawon yooku
kegbe po.
Odu ni Oloye Waidi Yusuf, Baale
Orile-Ilugun kii saimo foloko lagbo amuludun, oun ni oludasile ileese rekoodu
Olumo Record, o sig be awon olorin bii Alaaji Ayinde Barrister, Alaaji Ayinla
Killington, Ayinla Omowura, Admiral Dele Abiodun, Oloye Raji Owonikoko, Queen
Salawa Abeni, Oloye Oliver Coque, ati Oloye Morocco Maduka tiluu igbo atawon
mii in jade. Ojo keedogbon, osu kewaa, odun 1942 ni won bi Okunrin naa.
No comments:
Post a Comment