Lati le je ki alaafia joba ninu egbe roodu, ki nnkan si pada bo sipo gege bo se wa tele, igbimo egbe naa lapapo iyen Road Transport Employer Association of Nigeria, RTEAN ti kede Oluomo Akibu Titilayo, topo mo si Efele gege bi alaga tuntun ti yoo dari igbimo ti won sese yan.
Ninu atejade to te wa lowo, aare egbe naa
lapapo Alaaji Musa Muhammed ati akowe e, Henry Ejiofor Ugwu lo fowo sawon
igbimo tuntun naa pelu ase pe ki won loo bere ise ni kiakia.
Awon yooku ti
won tun yan lati je igbimo alamojuto naa ni Tiwalade Akingbade gege bi akowe
nigba ti Alaaji Kayode Inuolaji si je akapo.
Awon yooku tun ni Alaaji Rilwan Lamidi, Alaaji
Yinka Oshikoya, Oloye Segun Johnson,Ogbeni FOS Folarin, Alaaji Yaya Oriyomi,
Alaaji Muniru Jimoh, Alaaji Akeem Kolawole, Alaaji Monsuru Owookade, Dokita
Gbenga Odusanya, Ogbeni Segun Shabi, Alaaji Fatai Sanni ati Ogbeni Kayode Kehinde.
Alaaji Musa
Muhammed, aare egbe naa ti wa ro awon igbimo tuntun ti won sese yan naa pe ki
won rii pe won sa agbara won lati je ki isokan wa ninu egbe naa, ki won si sise
won gege bi ofin egbe se laa sile fun won.
Bee lo tun ro
won lati ri pe won fowosowopo pelu Gomina Dapo Abiodun ninu ijoba e, ki won si faye ore sile pelu
awon eeyan won lawon garaji to wa nipinle naa.
Ni bayii, Efele,
alaga igbimo alamojuto ti won sese yan ti mu dawon omo egbe naa loju pe oun yoo ri
pe alaafia joba ninu egbe roodu ati pe ko ni saye pe oun yoo maa da ijoba se.
O tun so pe gbogbo omo ni aye wa fun lati ri
oun fun idagbasoke ati ilosiwaju egbe naa. O wa lo akoko naa lati dupe lowo
aare egbe naa fun anfaani nla ti won foun atawon igbimo yooku pelu ileri pe
awon ko ni doju ti won.
No comments:
Post a Comment