Gomina Dapo Abiodun, tipinle Ogun,
ti gba gbogbo awon omo Naijiria nimoran lati ma se so ireti lori gbogbo ipenija
ti won koju lateyinwa pelu ileri pe o si n bo wa dara laipe
Gomina soro yii lakooko to n ba awon
eeyan soro nibi ayeye odun kokandinlogota ti orile ede yii gbominira, eyi to
waye lojo Isegun, Tusidee, ni papa isere M.K.O Abioola Stadiuum, Kuto,
Abeokuta.
O so pe pelu gbogbo isoro ti won n
koju lori oro aje ati ipenija nipa eto abo, o ni awon omo orileede yii si ni
emi igbagbo lati duro tii.
O tun lo anfaani ojo naa lati se
iranti awon asaaju wa lorileede yii lori bi won se ja fitafita lati je ki a gba
ominira, o ni o kan dun oun pe opo won ni ko si laye mo lati wo ibi ti
idagbasoke ati isokan de leyin gbogbo nnkan ti won ti foju winna lori ija
abele, oloogun ati oselu lati nnkan bi odun mokandinlogota seyin.
O ni"Ki orileede wa to le bori
awon ipenija to n koju wa lorileede yii, a gbodo koko mu oro eleyameya kuro, ki
gbogbo wa gbe pe okan naa ni wa, omo Naijiria si ni wa pelu.
" A gbodo je ki ife orileede wa
mu lookan aya wa, ka si fi gbogbo ara si nnkan taa ba n se labe bo ti wu ko ri.’
Dapo Abiodun wa gba gbogbo awon to
fee kuro lorileede yii lo sibo mii in lati duro sorileede wa ki won si fowosopo
pelu awon alase wa lati jo satunse orileede wa, ko si le ba awon yooku e kegbe
po.
O wa so pe gbogbo ona nijoba oun yoo gba lati pese awon
ohun imayederun gege bi ileri toun ti se pelu won, eyi ti yoo je ki igbe aye
nitumo sawon to n gbe nipinle Ogun.
O ni opo aseyori nijoba oun ti se
lenu ko pe toun gbakoso, o ni eyi ko tii to nitori erongba oun lati mu gbe
ipinle Ogun ga ju bo se wa lo, si n te siwaju.
Gomina wa mu dawon eeyan ipinle Ogun
loju pe igba otun yoo de bawon laipe nitori ijoba ko ni figba kankan fawon
nnkan to ba je mo eto won je won niya, o ni ko si nnkan to n je ojusaaju boya
nipa oselu, esin eleyameya atawon nnkan mii in, gbogbo araalu lawon yoo se
bakan naa laifi apakan da apa kan si.
No comments:
Post a Comment