Ojogbon Femi Fatade, oga agba nileewe poli
D.S. Adegbenro ICT , to wa ni Itori, nijoba ibile Ewekoro, nipinle Ogun, ti so
pe ko soooto ninu iroyin tawon kan gbe jade
lori ero ayelujara lori isakoso ileewe naa, o lawon obayeje kan lo wa nidii e
lati fi ba oruko awon alase ileewe ohun loruko je.
Iroyin naa to jade to pe akole e ni
egbe awon omoleewe poli lapapo NAPS, fesun
awon iwa buruku kan awon alakoso ileewe Poli ti won ti da sile lati bi
odun metala seyin.
Lara awon esun ti won lawon egbe
akekoo naa fi kan awon oga ileewe naa ni bi won se ni won fee fi kun owo ileewe,
gbigba owo abele lowo awon omoleewe naa atawon esun mii in.
Nigba to n soro nipa esun naa, oga
agba ileewe naa so pe ileewe naa ko tii fikun owo ileewe sugbon won n gbero
lati fi egberun marun un kun owo igbawole ati ikojade awon omoleewe.
Okunrin naa so pe awon alakoso
ileewe kan n bebe lodo ijoba ki won fawon laye lati safinkun awon nnkan mejeeji
naa.
Fatade tun salaye siwaju pe loooto
lawon ti ni lokan lati safikun owo ileewe fun ti eko 2019/2020 , eyi ti yoo bere lojo keje, osu kewaa, odun yii,
sugbon se nijoba dawon lekun lati ma se gbe igbese naa, o ni ki won wa bi won
se wa, tawon ko si yi oro naa pada.
O tun so pe iwadii toun se fihan pe
awon kan ti won ko fee ilosiwaju ileewe naa ni won ledi apo po mo awon omo
ileewe kan pelu lati ko awon alase ileewe naa si wahala, sugbon ti Olorun ko
fun won se.
O ni boun se wa yii, latigba toun ti
darapo mo ileewe yii, oun ko bawon da si oro oselu awon omoleewe naa, koda oun
kii bawon da si eni ti yoo je aare won pelu. Oun maa fi won sile lati se nnkan
won to fi mo inawo won.
Fatade wa so pe awon alakoso ileewe
naa je eni to pa ofin mo, to si n wa ojo iwaju, ti won je akinkanju, ti won si
n sise doju amin lati le ri pe ileewe naa wa nipo asaaju laarin awon elegbe e
lorileede Naijiria.
Ojogbon naa wa so pe gege boun se je alakoso,
onimo-eko, ati obi gbogbo agbara to wa nikawo oun pe oun fawon omoleewe nimo
eyi ti yoo wulo fun won lojo iwaju.
O ni gbogbo awon alakoso ileewe naa
ni won yoo sise po pelu Gomina Omooba Dapo Abiodun, lati rii pe eko di oun
irorun fun mutumuwa nipinle yii.
O wa gba awon akekoo atawon osise
ogba nimoran lati fowosowopo pelu awon alase ileewe yii, ki ileewe naa fi le
goke agba.
No comments:
Post a Comment