Komisanna awon olopaa nipile Ogun,
Basir Makama, ti gba awon alaabo ilu, So-Safe Corps nimoran lati lo idanilekoo
ti won se lati tubo je ki eto abo to peye wa fawon araalu.
Okunrin naa soro yii ninu ise to ran
sibi asekagba idanilekoo tawon oga So-Safe Corps se fawon osise won, eyi to
waye ni Training Academy, Ofada, nijoba ibile idagbasoke Mokoloki.
Arabinrin Oluseye Akinfolahan, to soju
komisanna awon olopaa nibi ayeye naa ro
awon osise alaabo naa lati lo iriri ti won ni lakooko idanilekoo lati je ki abo
tun loo soke lona lati daboobo emi ati dukia awon eeyan.
O gba won niyanju lati mu ise aabo
ilu lokunkundun gege bi won se finufedo gba ise naa, ki won si sa fun awonn
nnkan to le bawon loruko je.
Oga olopaa tun lo akoko naa lati
gboriyin fawon eso aaabo So-Safe Corps fawon aseyori nla ti won ti se lati pese
abo, ati pe ki won ma se je ki igbekele tawon araalu ni ninu won di ofo. O wa
ki awon olukopa naa ku oriire.
Ninu oro Arabinrin Olusola Osasona,
loruko ileese to n ri si ijoaba ibile ati oye jije nipinle Ogun, oun naa ro
awon olukopa naa lati lo ogbon ti won ko lakooko idanilekoo lati fi ran ijoba
lowo, ki won si se ise won tokantokan.
O to awon egberun mefa awon osise
alaabo yii ti won ti n kopa nibi idanilekoo, eyi to ti n waye lati nnkan bi ose
merin seyin, gbogbo eka ileese naa kaakiri ipinle Ogun ni won ti kopa ninu e.
Nigba to n baa won oniroyin soro
lori ayeye asekagba idanilekoo naa, Soji Ganzallo, to je oga agba fun ileese
So-Safe Corps dupe lowo Olorun fun anfaani to fawon lojo naa.
Bee lo tun dupe lowo Gomina Dapo
Abiodun fun anfaani to fun won lati le je ki ipese abo je awon logun ati pe
latigba tawon ti bere ni ijoba to wa lode yii, ti fawon ni atileyin.
Oga agba naa wa muu dawon eeyan loju
pe loorekoore ni idanilekoo bee yoo maa waye fawon osise ati pe Pataki ni eto
abo ile je fawon.
No comments:
Post a Comment