Inu idunnu nla ni Ogbeni Kehinde
Soaga, to je okan lara awon to n sagbateru awon osere Nollywood jade n dun, nitori bi won se ni
fiimu ere alawada iyen komeedi to se to pe akole e ni LAGOS NA WAH" wa
lara awon fiimu ogorun un ti BBC fun lami eye pe o dara ju
Ninu atejade kan ti okunrin naa fi
sita, lo ti so pe fiimu to ti se tipe naa wa lara awon eyi ti agbaye gbaa ninu
awon fiimu to dara ju ninu fiimu ogorun un akoko ti won sajo.
Odun 1994, ni okunrin naa so pe oun
gbe fiimu agbelewo naa jade, eyi to je pe oun loun ko, toun dari e, to si tun
je pe oun loun gbee jade.
Kehinde Soaga, to je omo igbimo to n
ri si awon to n sagbeyewo fiimu to n jade lorileede yii iyen National Films and
videos Censors Board. NFVCB so pe ohun iwuri nla lo je, oun si dupe lowo Olorun.
Okunrin naa wa so pe pelu aseyori
yii, oun yoo tubo lati maa tesiwaju nidii ise toun yan laayo yii.
No comments:
Post a Comment