Ajihinrere Damola Omonijo, gomina tuntun fegbe awon olorin emi iyen GOMAN, eka tipinle Ogun ti mu dawon eeyan paapaa julo awon e loju pe gbogbo ona loun yoo ki lati le je ki idagbasoke ati ilosiwaju ba egbe naa.
Ati pe akoko ise to wa niwaju oun ni
lati je ki ife ati irepo joba ninu egbe naa ki gbogbo awon ti won ti yapa tabi
fi egbe naa sile le pada sinu e lakotun,
Obinrin yii soro naa lakooko to n ba
oniroyin wa soro nibi ayeye ibura fawon oloye tuntun egbe naa, eyi to waye
niluu Abeokuta. Olorin emi naa tun so pe oun ti setan lati satunse ninu egbe
naa, lati ri pe oun mu awon omo egbe oun goke agba.
Ajihinrere naa tun te siwaju pe lara
erongba oun gege bi alaga egbe naa lati polongo oro Olorun nipase orin, ati lati je kawon omo
egbe oun naa maa dagba ninu emi,
Omo bibi ilu Ekiti, taa bi sinu
idile Oloye Ajibola ati Ajihinrere Funmilayo tun fi kun oro e pe isokan je
nnkan to je oun logun julo ninu egbe naa, idi niyii toun fi bere si ni igbe
igbese latigba ti won ti dibo yan oun gege gomina egbe naa tuntun nipinle Ogun.
O tun so pe ajosepo to danmoran lo
wa laarin awon ati gbogbo egbe lapao iyen PMAN. Lojo kejila, osu kefa, odun
yii, ni won dibo yan obinrin naa gege bi gomina egbe awon olorin emi, nibi ibo won to waye
niluu Sagamu. Oun si ni yoo je gomina keta fegbe GOMAN tipinle Ogun.
Awon oloye egbe yooku ni Gbadebo Odufuwa igbakeji gomina akoko,
Eunice Agboola, igbakeji gomina keji, Oyekunle
Osebunmi ni akowe egbe, Princess Busola Balogun, igbakeji akowe, Christy Fola
Bello ni akapo. Bunmi Leramo- ayewe owo wo. Olufemi O. Oyedele, ni alukoro,
Awon yooku ni Imole Ogunwolu amofin,
Olayinka Bello Welifia akoko, Mary Gbadebo, Welifia keji, Gbenga Afuwape, alakoso nipa
erongba ati Bisayo Omogoriola, alakoso eto iroyin
Lojo keta, osu yii, ni won se ibura
fawon oloye tuntun naa nile ijoba to wa ni Isale igbeyin niluu Abeokuta, Aare
egbe naa, Funmi Aragbaye, lo wa se ibura fun won lojo naa.
No comments:
Post a Comment