Gomina Dapo Abiodun tipinle Ogun, ti seleri pe erongba eto isuna fodun to n bo yoo je eyi topo e yoo wulo fawon eeyan ipinle naa.
O seleri yii
lakooko to n bawon eeyan soro nibi ipade gbongan lori bi eto isuna odun 2020
naa yoo se lo, eyi to waye ni Ijebu Ode fun agbegbe Ogun East.
O sakiyesi pe
eto isuna ipade gbongan tawon se yii yoo ran ijoba lowo lati mo awon nnkan ti
won le se fawon araalu ti yoo mu iderun ba tile toko.
Dapo Abiodun
tun so ninu oro e pe o se pataki fun ijoba lati maa je kawon araalu mo bo ba se
n lo lati le jo jiroro lori ona ti won le gba lori isuna ipinle naa.
Bee lo
tun so pe ipade pelu awon araalu ni gbongan yii tun duro fun bi isakoso ijoba
to wa lode yii se n gbiyanju lori isejoba rere fawon araalu.
O ni “Igbgbo
mi ni pe awon araalu yoo nikan lati so nipa ara won, nitori idi eyi, aye yoo wa
fun lati se nnkan tooto ninu igbese ijoba awarawa.
Dapo Abiodun
tun so pe igbagbo oun tun ni ninu si se awon nnkan tawon n se yii, imurasile
fun eto isuna yoo je ireti rere fawon araalu ti won yoo si nigbagbo ninu ijoba
O tun soo di mimo pe ijoba ti seto awon ise
akanse to yoo kaakiri ekun meteeta to wa nipinle naa
Gomina tun ni
“ Mo fee ki e mo daju pe ijoba to wa lode yii, ijoba yin ni, o wa fun yin,
nitori idi eyi, ki awon to wa ni Ogun Central ati Ogun West naa maa gbaradi fun
iru ipade bayii.”
O wa lo akoko
naa lati pe gbogbo awon alabasise po ijoba lati fowosowopo pelu ijoba ki
erongba lati le mu ilosiwaju ati idagbasoke ba ipinle naa fi le te siwaju.
Gbogbo awon
ti won soro nibi ipade naa lo fi aidunnu won han si ipo tawon ona wa paapaa ni
Ogun East yii, ti won si ro ijoba lati satunse nipa eto isun odun to n bo naa.
No comments:
Post a Comment