Ijoba ipinle Ogun febi So-Safe Corps to ku ni milionu kan naira - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 13 October 2019

Ijoba ipinle Ogun febi So-Safe Corps to ku ni milionu kan naira


Ijoba ipinle Ogun, labe akoso gomina Dapo Abiodun, ti fun ebi osise alaabo So-Safe Corps, Kehinde Aigbe ni ebun milionu naira kan fun ti okunrin naa to doloogbe lakooko tawon adigunjale yinbon mo on nigba to wa lenu ise.
       
Ogbeni Kunle Osota, to je akowe agba nileese ijoba ibile ati oye jije nipinle naa lo mu sowedowo naa fun Major Kingsley Aigbe to je okan lara ebi e, eyi to waye ni gbongan Obas’ Complex, Abeokuta .

Iwaju iyawo atawon omo meji ti okiunrin naa fi sile saye lo ni won ti gba sowedowo naa, nigba to n soro nibi eto naa, Olusola Osasona to soju alakoso ileese ijoba ibile so pe awon ti koko na egberun lona eedegbeta naira fun okunrin nigba ti isele naa waye fun itoju.

O ni ijoba se nnkan kekere naa lati fi ran ebi ati iyawo pelu omo meta to fi sile lo lowo.Ninu oro oga agba fun So-Safe Corps, Soji Gazallo, dupe gidigidi lowo ijoba ipinle Ogun lori akitiyan
  .
          
In his remarks, the Commander of the Corps, Soji Ganzallo lauded the effor won nigba ti isele naa waye ati titi di akoko yii, o wa seleri pe ileese alaabo ilu naa ko ni rewesi nipa eto abo won fawon araalu. Nipinle Ogun.
          
Bakan naa, Major Aigbe, dupe loruko  molebi won lowo Gomina Dapo Abiodun ati oga agba So- Safe Corps fun inawo won ati bi won se duro ti ebi won lakooko ti nnkan naa fi sele.

A o ranti pe lojon keji, osu kefa,odun yii lawon adigunjale yinbon mo Kehinde Aigbe to je osise So- Safe Corps, l;akooko ti won koja awon adigunjale ni ona Olorunsogo, Oke-Lantoro, niluu Abeokuta,
Loju ese ti isele naa waye ni won ti sare gbee lo si osibitu lati gba emi e la, o lo aimoye ojo ko to di pe won tun gbe lo si osibitu LUTH niluu Eko, ko to di pe o wa pada ku leyin igba to dele.

No comments:

Post a Comment

Pages