Egbé awon odo nijoba ibile Ipokia
nipinle Ogun ti yari mo oga agba fún ileese kositoomu lọwọ pe dandan a fi ti
won ba fa dereba to pa Daniel Opeyemi Odusina sile láàárín wakati
mejilelaadorin.
Gege bi atejade tegbe odo náà fi
sita lakooko ti won lòó ki awọn obi Daniel ni won ti so pe wahala n bò bi oga
agba awon kositoomu ba ko lati fa dereba naa sita.
Won fi aidunnu won hàn lori isele to
mu emi Daniel omoleewe gírama Ojumo community High School, ni Ihunbo ti won ni
dereba kositoomu naa pa lakooko ti won le awon onifayawo lo.
Danieli yii lo je akọbi fún
Arákùnrin ati Arabinrin Adigun ati Adejoke Odusina.Ile won to wa ni
Ikorodu Asipa, Ihunbo/ilase. nijoba ibile Ipokia
Ogbeni Deji Imoleayo Mawutin to je
adele alakoso tun bebe pe ki gbogbo awon eleto abo ti won ko nii oye lori iṣẹ
wọn kuro ni awọn ala ti won wa.
O ni bi won ba wa ko ti won ko gbe
igbese naa laarin wakati mejilaadorin nnkan ti won ba ri, ki won fara mọ nitori
awon ko le gba bi ifemisofo se n fi gbogbo igba waye latowo awon kositoomu yìí.
Àwọn odo náà tún dé ilé mọlẹbi
Kikelomo Babalola toun naa farapa nibi isele, to sì n gba ìtọ́jú lowo.
Egbé òdó náà tún fikun oro won pe
ohun tawon bebe yii yóò mú ìdájọ wà fún iku airotẹlẹ ti won fi pa Daniel
Opeyemi pẹlu iwakuwa awọn dereba kositoomu lagbegbe yii.
No comments:
Post a Comment