Seneto Tolu Odebiyi ki Dapo Abiodun ku oriire ti idajo ileejo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 15 September 2019

Seneto Tolu Odebiyi ki Dapo Abiodun ku oriire ti idajo ileejo


 
Asofin  Tolulope Odebiyi, to n soju ekun Ogun West  nile igbimo asofin agba niluu Abuja, ti sapejuwe bi Dapo Abiodun, gomina ipinle Ogun se bori ejo ti Akinlade ti egbe oselu APM pee gege bi igbagbo ninu ofin pe idajo ododo n joba lorileede wa.

O soro yii ninu atejade kan to gbe e jade lati fi ki Gomina Abiodun ku oriire bo se ja ajabo ninu idajo ti igbimo to n gbo ejo lori ibo gomina to waye ninu osu keta, odun  yii gbe jade lanaa.

O so pe oun tun fi sori ife ati igbagbo ninu Olorun fun atileyin awon eeyan ipinle Ogun ti won ni fun Abiodun lo mu ajoyo nla naa waye.

Seneto naa tun so pe lai se iyemeji aseyori naa lagbara, to si ye keeyan dupe lowo Olorun le lori ni. Bo se wa n ki Abiodun ku oriire bee naa lo tun ki egbe oselu All Progressive Congress (APC) lapapo naa ku oriire nla ti won jo se po naa.


No comments:

Post a Comment

Pages