Egbe oselu Laboor tipinle Ogun ti
ranse e ku oriire si Omooba Dapo Abiodun, fun ti aseyori to se nileejo lori
bawon igbimo to n gbejo lori ibo gomina ninu osu keta, odun yii, tun se so pe
oun ni lo wole gege bi gomina ipinle Ogun ninu idajo ti won gbe kale.
Ninu atejade ti Sunday Olaposi
Oginni, to je akowe egbe naa fi sita laaaro ojo Aiku, Sannde yii loruko awon
oloye atawon ojulowo omo egbe naa lo ti lawon ba Gomina naa yo.
O so pe idajo to waye naa fihan daju
pe loooto lawon eeyan ipinle Ogun dibo fun Omooba Dapo Abiodun ninu ibo gomina
to waye lojo kesan, osu keta, odun yii laisi wahala kankan nibe
Bee lo tun so pe awon tun ki awon oloye egbe oselu APC lati ori alaga won
Oloye Yemi Sanusi, Ayo Olubori ati Ogbeni Tunde Oladunjoye fun ise takun takun ti won se ninu egbe naa
lati le je ki Dapo Abiodun saseyori lakooko ibo to gbe okunrin naa wole gege bi
gomina.
Oginni tun dupe lowo Oloye Olusegun
Osoba, gomina tele nipinle Ogun to tun je olori egbe naa fun aseyori ti won jo
se naa.
O wa lo anfaani naa lati ro egbe
oselu APC ati Gomina Dapo Abiodun pe ki
won lo aseyori ti won se naa lati ri pe atileyin ti won ri gba lati odo egbe
oselu yooku ko ja si asan.
No comments:
Post a Comment