Iyeru, adele alaga fegbe awako NURTW nipinle Ogun ba Dapo Abiodun yo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 15 September 2019

Iyeru, adele alaga fegbe awako NURTW nipinle Ogun ba Dapo Abiodun yo


Alaaji  Akeem Bodunrin, topo awon eeyan mo si Iyeru, to je adele alaga fegbe awon awako NURTW, nipinle Ogun, ti ki Gomina Dapo Abiodun ku oriire bo se jawe olubori ninu idajo to waye lana an niluu Abeokuta.

Gomina Abiodun nileejo da lare pe ko maa se gomina e lo nigba ti igbimo to n gbejo naa fagile ejo ti Akinlade tegbe oselu APM pe ti won ni ko lese nile.

Ninu atejade ohun ni oga awon onimoto naa ti so pe oun ba gomina naa yo fun isegun nla ati aseyori to se nibi igbejo naa.

Bee lo so pe idajo to waye je idajo ododo ti ijoba tiwa-n-tiwa lorileede yii n fee, o wa fi akoko naa ro awon eeyan ipinle Ogun lati gbarukutu ti isakoso ijoba Abiodun.

Bakan naa lo tun gba awon eeyan nimoran lati fowosowopo pelu e ati pe awon aseyori e laarin ogorun un ojo to ti figba joba ti fihan pe o ni ero rere fawon araalu.

O ni oun mo pe o si ni awon nnkan gidi lokan lati gbe awon okoowo ati ileese-nla wa sipinle naa, bo se n ki awon araalu lo ni oun tun ba awon eeyan ipinle Ogun yo pelu.


No comments:

Post a Comment

Pages