Gomina soro yii lakooko to fi iduunu
e han lori bile ejo se daa lare ninu igbejo to waye lanaa, Satide, Abameta. O so pe oun ka
idajo naa kun aseyori fun ijoba tiwa-n-tiwa.
Ninu atejade kan ti akowe iroyin
gomina naa, Ogbeni Kunle Somorin fi sita lo ti so pe oun ro awon akegbe oun
ninu egbe oselu Allied Peoples Movement (APM) lati gbagbe nipa ibo 2019 ki won
si je kawon jo fowo sowo po pelu ijoba e lati tun ojo iwaju ipinle naa se papo
gege bi erongba e.
O tun gba won niyanju pe kaka ti won
yoo maa fi sun owo nina tabi fakoko sofo, ki won je kawon jo soro bi won yoo se
pada sinu egbe All Progressives Congress (APC) nibi to ni won ti bere tabi ki
won kuku loo bere si nii murasile fun
ibo fodun 2023.
Dapo Abiodun tun so pe " Aye wa
fawon oludije fegbe oselu APM atawon omo
egbe oselu yooku lati darapo mo wa ni APC. Mo fee kawon to si n binu mo pe
ijoba tiwa-n-tiwa je ti gbogbogboo lati sakoso.Awon eeyan ti soro bee ni igbejo
si ti jeri si pe emi ni mo bori, enikeni ti ko ba si dun mo ko loo bere
igbaradi fodun 2023"
No comments:
Post a Comment