Apapo egbe oloselu ti won foruko sile nipinle Ogun
ti fi idunnu won han si abajade idajo ibo gomina to waye lojo Abameta, Satide,
to koja yii, nibi ti won ti fagile ejo ti Akinlade tegbe oselu APM pe Gomina Dapo Abiodun.
Gege bi atejade ti Otunba Mosuro
Adebayo, Alaaji Moshood Adesina ati Oginni Olaposi Sunday fowo si laaaro ojo
Aje, Monde, nibe ni won ti ki Gomina Dapo Abiodun ku oriire ajabo to jabo nibi
igbejo naa.
Won ni idajo to waye naa, eyi ti
Adajo Halilu saaju fun fihan daju pe loooto ni awon eeyan ipinle Ogun dibo fun
Omooba Dapo Abiodun gege bi gomina lojo kesan an, osu keta, odun yii.
Bakan naa lapapo egbe oselu naa tun
ki Oloye Yemi Sanusi, Ayo Olubori ati Tunde Oladunjoye ti won je oloye egbe APC nipinle Ogun fun
akitiyan lati ma se je kawon modaru ti won sise tako egbe naa bori, ti won si
je ki Omooba Dapo Abiodun saseyori
lakooko ibo naa.
Won tun so ninu atejade naa pe pelu
ajosepo ti won ni pelu apapo egbe oselu fihan daju pe awon oloye egbe oselu APC
sise takuntakun lati rii aseyori ibo gomina naa waye laisi wahala tabi idaamu
kankan lakooko naa.
Bee naa ni won tun lo anfaani naa
lati ki Aremo Olusegun Osoba ku oriire fun ipa baba pelu ogbon imo ati oye to
mu won saseyori abajade esi idajo naa.
Apapo egbe oselu naa tun wa gba
Onarebu Adekunle Akinlade ti egbe oselu APM nimoran lati ma se pinnu pe oun yoo
pejo ko-te-mi-loru, won ni tete ni oselu, eni to ba padanu lonii, le fidi remi
lola.
Won wa ro egbe oselu APC ati Gomina Dapo
Abiodun lati lo aseyori ti won se lati rii pe awon to binu kuro ninu egbe APC
loo si APM , ki won dawon po, ki won le di ebi kan.
Won wa ni ki Dapo Abiodun ma se je
ki wahala awon apapo egbe oselu latigba ti won ti bere di akoko yii ja si asan
No comments:
Post a Comment