Onarebu Kelani Lukaman Taiwo topo
awon eeyan mo si KELAT, to je oludije
fun ipo alaga ijoba ibile ni ekun Abeokuta South, labe egbe oselu APC, ti ba
Gomina Dapo Abiodun yo ayo nla fun aseyori to se nibi idajo ileejo to gbo ejo
nipa ibo gomina to waye ninu osu keta odun yii.
Gege bi atajade ti okunrin naa fi
sowo, lo ti ki Gomina ku oriire bee lo si tun ki egbe oselu APC tipinle Ogun
naa ku ayo nla naa
O so pe idajo to waye naa tun je
kawon eeyan nigbagbo pe idajo ododo si wa nile wa ati pe yoo tun je kawon eeyan
nigbekele ninu awon Adajo wa.
KELAT tun fi kun oro e pe latigba ti
igbejo naa ti n loo lowo lawon onwoye kan ti mo pe Akinlade to pe ejo atawon
eeyan e kan fee fi akoko sofo ni, nitori Olorun ko si leyin alabosi.
O wa ro Gomina Abiodun lati maa te
siwaju ni awon aseyori to ti n se paapaa julo laarin ogorun un akoko to lo
saaju. O wa gbadura pe ki Olorun tubo maa ran lowo.
No comments:
Post a Comment