Oga agba fawon fijilante ti Naijiria
ti iha Ali Sokoto nipinle Ogun, Ogbeni Adegbenga Adesanya, ti so pe Ogbeni
Nureni Adedoyin, toun naa pe ara e ni oga fijilante ni isoro kan soso tawon ni
nipinle Ogun ati ki i sojulowo omo egbe.
Okunrin naa soro yii lakooko to n
oniroyin wa soro, o ni bi okunrin naa se ba fijilante tipinle Ogun ti won pe ni
VSO to di So-Safe Corps bayii je ti won fi le danu lo se tun fee ba fijilante
ti Naijiria to wa nipinle Ogun je.
Oga fijilante naa so pe gbogbo awon
to mo ipile fijilante latile mo pe iro ni Adedoyin n pa, odo Ganzallo to je oga
agba VSO ti won di So- Safe Corps, lo so pe o wa tele ati pe onifayawo ti won
maa n gbe moto tokunbo wa lo n se tele.
Adesanya tun salaye pe ‘Dereba
Birisiyu to je oga VSO tele ni Adedoyin, igba naa ni Ganzallo fi n fa kaakiri,
awa si duro lori owo wa ti fijilante Naijiria, to je ti Baba wa Ali Sokoto, Oun
lo so foruko ileese wa yii sile labe ijoba.
O ni odun 2017 ni okunrin naa wa ba
enikan ti won n pe ni John Soremekun pe oun
fee darapo mo wa, nitori ki toun ma baa gbe, o loun si so nigba naa
lohun pe oun ko le gbaa wole nitori Jahun lo n tele.
O ni gbogbo ona ni won wa lati je ko darapo mo
awon tin Sokoto sugbon oun ko jale, debi pe won tun lepa emi oun nigba naa. Idi
niyii to fi ni Adedoyin yii fi loo ba Jahun.
Adesanya tun salaye pe Jahun ti won
so nipa e yii akowe lo je fun Ali Sokoto, ko to di pe oun fee gba Fijilante naa
mo eni to foruko e sile lowo.
Bee lokunrin yii tun so pe gbogbo
ona lawon mejeeji fee fi wa nisokan, nigba ti Gomina Dapo Abiodun so fawon pe
boun ba fee bawon se po a fi kawon di okan soso, eyi lo so pe o mu awon
agbaagba ninu igun mejeji fi wa ona lati je kawon di okan soso.
O ni idi niyii tawon fi bere igbese ati
pe o je edun okan fawon pe Adedoyin yii naa lo ni ko le seese, nitori ipo oga
lo n wa, o ni nnkan to se ni VSO naa niyen, to so pe o n ba Gazallo, oga e je,
idi niyii to lawon yen fi lee danu.
Adesanya tun salaye pe nigba ti won
le dani tan nijoba so pe ki enikeni ma baa se, o lawon ti Sokoto Alli ko ba se,
idi niyii to ni o fi loo ba Jahun.
Okunrin naa tun salaye pe opo aseyori
lawon ti se nipinle Ogun gege bi fijilante fun apeere, o ni ni Robiyan, Alabata
atawon ibo mii in, o lawon olopaa gan an le jeri si.
O so pe egbe fijilante todo ti Ali
Sokoto, ki i se onijagidijagan lati dabo ru, idi niyii to lawon fi n se awon
nnkan tawon n se pelu suru/
Pelu e naa lo ni awon je kawon
agbofinro, otelemuye atawon olopaa mo bi nnkan se n loo. Fun apeere o ni redio
Family FM lokunrin naa n lo tele, awon ti ko leta si won pe won n te ofin loju,
won ki i se ojulowo fijilante.
O ni okunrin naa ti sa kuro nibe
Sweet FM lo n lo awon si ti so fun agbejoro won ko gbe igbese lee lori.
Oniroyin wa pe Ogbeni Nureni
Adedoyin, eni ti won fesun kan, lojo Eti, Furaidee, o so pe oun fee de Ibadan, toun ba de lojo keji oun yoo pe wa, nigba to di aaro yii, iyen ojo Isegun, Tusidee, ni nnkan bii aago mesan ku iseju metalelogun, a tun pe e ko to di pe a gbe iroyin naa jade,sugbon ko gbe ipe wa.
No comments:
Post a Comment