Lojo Isegun, Tusidee, lawon Baale
mefa kan ti won wa lati ilu Itele, nijoba ibile Ado-odo-Ota, nipinle Ogun, sabewo
wa sodo Aare tele lorileede yii, Oloye Olusegun Obasanjo, ni gbongan Oke-Ona
Hall, Green Legacy Resort ni OOPL, niluu Abeokuta,
Awon Baale mefeefa tuntun ti won
sese yan ti won wa naa ni Oloye Adelaja F. Fasina lati Iliwo, Oloye Monsuru
Olayinka Balogun to wa lati Ilekem),Oloye
Owotolu Kazeem toun je tie ni Ijana, Oloye Fatai Akapo lati Isunba, Oloye
Rasheed Ajasa ti Ipotobo ati Oloye Lateef Rufai toun naa je Baale ni Olugbode.
Awon mefa ninu awon meje ni won wa,
nigba ti eleeje won ti won so pe o wa lati Iga, Ilegbede ni won so pe won ko tii yanju eni to ye nipo
naa ;ohun, nitori ikunsinu ti won lo wa
laarin won.
Ninu oro Obasanjo nigba to n ki won
kaabo, o fi idunnu e han si bi won se yanju wahala to n sele laarin ara won fun
bi odun meloo kan seyin ni Itele.
Bee lo tun dupe lowo iko e, eyi ti
Oloye Abraham Idowu Akanle saaju fun gege bi asoju gidi lori aseyori won bi won
se yanju gbogbo rogbodiyan naa, ti won si je ki alaafia joba.
Obasanjo tun so pe"Mo fee dupe
pupo gidi lowo yin fun bi e se je ipe alaafia yii, bo si se ye ko ri niyen,
Agbami ni wa, nigba mii in a o san sapakan, tawon mii in yoo fo sapa mii in,
sugbon bo ti wu ko ri a maa san pade ara wa ni, Se a wa ko lati pade bi akoko
ba to?.
"Nitori idi eyii, lati akoko
yii lo ko si wahala tabi ija mo. A ni lati sun siwaju gege tegbon taburo ni Itele."
O ni ‘Bi ki i ba se pe ko fi bee si
aye, o wu mi ki n wa pelu yin, sugbon mo tun fee rin irinajo, ti won si ti n
duro de mi bayii. Sugbon aburo mi yoo gbakoso, Leekan si. Mo dupe fun ipe
alaafia yii ti Olorun so pe o seese niluu Itele yii.
Gbogbo awon agbaagba atawon asaaju
ti won soro lojo naa ni won gboriyin fun Obasanjo lori bo se gbe igbese lati le
je ki alaafia waye, pelu bi won ti sagbara e tele sugbon ti ko bo si.
Ninu oro ti Oloye Yaya Oyewole ti
won pe ni Baba Odan, O ni ohun itan ni nnkan to waye lojo naa, inu awon si dun
pe ogun ti tan niluu Itele, o ni oun le so pe inu oun dun pe loju emi oun ni
ija naa ti pari.
Alagba Samuel Olatunji Asorobi, so
ni tie pe o to eedegbeta milionu naira tawon ti padanu lori wahala to ti sele
lati nnkan bi ogoji odun seyin laarin ara won sugbon ti itan ti wa yi pada
bayii nipase Obasanjo. O lawon ko nii gbagbe titi lae.
Akanle ni tie ro awon Baales tuntun ti won sese yan lati jo sise po ki
idagbasoke le de ba ilu Itele.
Bee lo tun lo akoko naa lari ro
gbogbo awon tinu n bi lati gbagbe gbogbo nnkan to ti sele seyin ki alaafia le
joba. O ni akoko ti to lati je ki ilu Itele te siwaju pelu igbagbo pe awon ko
ni kabamo nnkan tawon se lojo naa,
No comments:
Post a Comment