Se ni gbongan asa ibile Cultural Centre, to wa ni Kuto, niluu Abeokuta kun
fo-fo-fo lojo Isegun, Tusidee, nigba ti Gomina Dapo Abiodun sagbekale isin ope
ati iyin fun bo se jawe olubori nibi idajo igbimo to n gbo ejo gomina to waye
lojo Abameta, Satide, to koja yii.
Bawon olori elesin musulumi se wa
nibe bee lawon onigbagbo naa ko gbeyin, to fi mo awon elegbejegbe kaakiri
ipinle naa ni won wa ba Gomina Dapo Abiodun sajoyo bo se moribo naa.
Awon olorin emi bii Tope Alabi,
Lanre Teriba, Saoti Arewa, olorin musulumi atawon mii in ni won wa nibe ti won
forin da awon eeyan laraya.
Ninu oro Gomina lo ti dupe lowo
Olorun lori bo se ko o yo ninu ejo naa,
o lawon sagbekale eto naa lati fi mo riri oore ti Olorun se fun un.
Bakan naa lo lo akoko naa lati so
fawon eeyan ipinle Ogun pe isakoso ijoba oun ti bere igbese lati maa ko awon
ile alakotunta fawon eeyan ipinle naa lowo ti ko nii koja agbara won.
O fikun oro e pe ile alakotunta naa
tawon bere e yii ni yoo tun pese ise fawon birikila, kafinta, apoda atawon
osise yooku tawon naa yoo le rowo mu lo sorun.
Bee naa ni Abiodun tun lo akoko naa
lati so awon aseyori e laarin ogorun ojo ti won de ijoba. O run so pe adehun
tun ti n lo lowo lati bere atunse awon ona bii Ijebu-Ode si Epe, nigba to ni
ipinle Ogun ati ti Eko naa ti setan lati jo sise po lori ona Abeokuta-Ifo-Ota ati
Sagamu- Ikorodu.
Gomina tun so nipa eto eko pe ijoba
oun ti bere awon ileewe alakobere to lenigba ati ile itoju fawon alaisan.
O wa ro awon eeyan lati maa dupe
lowo Olorun nigbakugba, ki won si maa wa ojurere e pelu, o wa seleri pe ijoba
oun ti setan lati pese isakoso rere mu oun lokunkundun,
No comments:
Post a Comment