PCRC ni ki oga fijilante nipinle Ogun toro aforiji - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 3 September 2019

PCRC ni ki oga fijilante nipinle Ogun toro aforiji



Egbe awon araalu to n sise po pelu awon olopaa nipa oro abo ilu, iyen PCRC nipinle Ogun, ti ro oga agba fajo alaabo ilu, So- Safe Corps, Ogbeni Soji Ganzallo, lati  je ki oga agba fun ileese awon fijilante tile Naijiria ti eka ipinle Ogun, Ogbeni  Nureni Adedoyin toro aforiji lori esun to fi kan So-Safe Corps lori isele to waye nibi tawon meta kan ti pa omoleewe Yunifafisiti OOU, Ago Iwoye.

Oro yii jade lakooko tawon omo egbe naa sabewo loo sodo Oga So-Safe Corps, ni ofiisi e lati fi atileyin won nipa ise ti ajo alaabo naa n se nipinle Ogun, ati lati  bu enu ate lu oro ti won ni Adedoyin, oga agba awon fijilante naa so gege bi ibaniloruko je, ko si tete toro aforiji.

Ninu oro Ogbeni Yomi Whyte, to je alaga fun agbegbe Abeokuta egbe PCRC, lo ti gba Gazallo niyanju lati rii pe Adedoyin toro aforiji naa, nitori igba akoko ko ree, to ti maa n pariwo enu kaakiri, lori oro ti ko sooto nibe.

Nigba to n ka apileko loruko egbe naa, Ogbeni Femi Adegoke so pe awon wa kii Gazallo ni ofiisi e lati fi atileyin won han si oga agba naa ati fun gbogbo osise So-safe Corps nipinle Ogun.

Bee lo tun so pe awon wa lati wa fi igbagbo won han si okunrin naa lori  awon ise takuntakun tileese naa n se lati fi okan awon araalu bale nipa eto abo.

Okunrin naa tun so pe ise tajo So-Safe n se nipinle Ogun ko see lafiwe latigba ti won ti wa, ti won n gbogun tawon orisiirisii awon iwa ibaje kaakiri.

Bee lo ni egbe PCRC naa mo ipa ti egbe alaabo naa ko lati pese abo fawon araalu. Ni ipari lo ti so pe awon gbegile gbogbo ona tawon kan fee maa lo lati ba ajo So-Safe Corps loruko je.

Ninu oro e, Oga agba fun So-Safe Corps, Soji Ganzallo, femi imoore e han lori irinajo pajawiri ti egbe naa se wa sodo e. o ni ohun ijoju nu.

Bee lo so menuba nipa isele to waye naa, nibi ti komisanna fawon olopaa nipinle Ogun ti safihan awon meta kan to pe ni fijilante, ti won lawon tun je Yaluwon.

O ni nibi ipade eto abo tawon se lowo lojo naa, ni won ti ko awon eeyan naa de, ti won si safihan won pe fijilante ni won. O ni o wa je iyalenu bi Adedoyin se pe ipade oniroyin, to pariwo pe So- Safe lawon ti won mu naa.

Gazallo tun so pe oun ati komisanna awon olopaa nipinle Ogun naa si pade nibi ipade aabo ilu to waye ni Ibadan, to foun se yeye pe oun loun rowo raye, toun fesi.

O ni Komisanna si so foun pe awon meta toun safihan won pe fijilante ni won, kilode ti won ko se wa koju oun.Okunrin naa ni kii se igba akoko Adedoyin leleyi, o ni igbakeji oun ni tele sugbon nitori asemase to se ninu egbe ni won se le danu nigba naa.


O ni latigba naa lo ti so awon di orogun, to n bawon je kaakiri. Lori pe ki oga agba fijilsante naa toro aforiji, Gazallo so pe awon ti n gbe igbese pelu loya won, tonitohun si ti fun un lawon akoko kan lati satunse.

O ni tojo naa ba pe ti ko toro aforiji, o ni awon yoo foju e bale ejo fun esun ibaniloruko je. 


1 comment:

  1. If all errors made by dealers resulted in a 1 % overpay of complete payoffs, roulette’s mathematical advantage would drop from 5.26 % to 4.34 %. Using this error estimation methodology, a 5 % mistake fee would render the game almost even cash. Remember, it will be to be|will probably be} the bigger payouts, not the smaller ones, that might be susceptible to errors. A majority of the errors happen when either an under-experienced supplier or a supplier buried in a excessive chip action game makes calculation errors. Errors may be} frequent are overpayment that results from addition errors or from utilizing the incorrect “key” to estimate the total payout. Other than incorrectly calculating the total payout of the same color, errors are made by overestimating the proper number of 20-chip stacks 카지노 needed for the payout.

    ReplyDelete

Pages