Omo So- Safe Corps ni olori odo, tawon olopaa muu pe o paayan nijebu Igbo- Adedoyin - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 31 August 2019

Omo So- Safe Corps ni olori odo, tawon olopaa muu pe o paayan nijebu Igbo- Adedoyin


 
Lana an, la gbe iroyin kan jade lori ipade oniroyin ti Soji   Ganzallo, to je oga agba fun ileese alaabo So- Safe Corps, tipinle Oguni, se nibi to ti fesun kan Nureni Adedoyin. oga fawon  fijilante Naijiria pe o fee bawon loruko je ni bo se so pe awon omo abe oun mo nipa bi won se pa omoleewe, oni ipele kerin,ti yunifasiti Olabisi Onabanjo, ni Ijebu Igbo.

Sugbon Okunrin oga agba fajo fijilante Naijiria si tun tenu mo pe nnkan to da oun loju ni pe omo eso alaabo So-Safe Corps ni Idowu Oyedele, tinagije n je olori odo, o loun mo mo nipa e daadaa, toun gan-an si tun jewo fawon olopaa pe So- Safe Corps loun, ti won ri kaadi idanimo ati ibon ti won ko oruko egbe naa si.

O soro yii lakooko to n forojomitoro oro pelu oniroyin wa ni ofiise e, loni in, niluu AbeokutaO ni ‘Nigba ta fi wa ni fijilante tipinle Ogun, omo leyin Gazallo ni, nigba ti won si loo si So-SAFE Corps, won jo loo ni, koda olori odo so fun mi pe ibi ti Gaxallo ba lo loun lo. Omo So-Safe Corps ni’.

Gege bi apeere, o so pe lenu ojo meta yii loun si pade olori odo yii ni Ijebu Igbo, nigba ti okan ninu awon oba Ijebu North,  ni Eruwon, pe oun toun si loo je won.

Adedoyin ni’Nigba taa fee de be, mo de ikorita kan, awon eeyan mi  naa wa nibe, mo duro lojo naa, ti mo ba olori odo soro pe ki won rora maa se jeje o, ki won ma se ise ti ofin ko gba won laaye, se won mo pe won ti kuro ninu fijilante, Oun gan-an naa si tun so fun mi pe Gazallo lawon baa lo, mo sa so fun pe ki won maa se jeje’.

‘Kabiyesi tie beere pe sara wa ni won, mo si so fun won pe won ki i sara wa sugbon ti won ba fee darapo mo wa, a maa sayewo won finnifinni’

Lori idi ti oro naa fi kawon lara, oga agba fijilante Naijiria yii so pe ‘Ni akoko iyalenu lo je fun wa nigba taa ri ninu iwe iroyin oloyinbo Punch, pe won fesun apaayan ati adigunjale kan awon omo egbe wa, o ya wa lenu lati gbo iru e, nitori egbe fijilante tile Naijiria, egbe to foruko sile labe ileese CAC ni. E si mo pe egbe to ba ti forukosile labe ijoba, lo ni egbe naa, ohun ti won ba ti so nipa egbe yen, o ti kan wa niyen o’.

O ni ka ni won ko daruko fijilante ni, ko nii kan awon rara sugbon bi won se figbe oruko egbe won bonu lo je kawon naa ya tete pariwo sita.

“Awa naa wo awon ti won daruko yen, a ri i pe won ki i sara wa, nitori a niwe tawon omo egbe foruko si lapapo, ta n pe ni database loyinbo. Awon kan wa ti won wa nibe ti won maa sayewo oruko tiru nnkan bee baa sele, oruko awon ti won daruko yii ko si nibe’.

‘Eleekeji ni pe  ninu iroyin yen, ni won ni okan ninu won ti so pe omo egbe So-Safe Corps loun, idi ta a fi so pe ki i se omo egbe wa nitori iyato wa laarin wa ati So-Safe Corps’.
 Bee ni Adedoyin tun so pe awon naa tun loo sibi ti won ni isele naa ti waye, awon yen so pe won ki i somo egbe awon.

Lori Yaluwon tawon yen lawon n je, O so pe ‘A ti gbo nipa Yaluwon tele, taa si maa n so won, a maa fi n to awon agbofinro leti bi nnkan ba se n lo, awon ti won pe ni Yaluwo, a ko mo bi won se je, nitori won ko si laarin wa.

‘Fun apeere, awon kan wa ni Ikenne, nigba kan ti won pe ara won ni Ikenne Security Council, ti won wa foruko sile lodo wa, sugbon nigba to ya won lawon ko ba wa se mo nitori ofin wa ti le ju’.

‘Nitori awa ko faye gba keeyan maa foruko egbe yii huwakuwa. Won gba ibomin in lo, nitori gbogbo wa la leto labe ofin lati se nnkan to ba wu wa. Yaluwa kii sara wa, won ko si pe ara won ni fijilante, bawon olopaa se pe won bee ni o ya wa lenu’.

O wa fesun kan awon to gbe iroyin naa jade pe o ye ki beere nigba ti won fun won niwe ti won ko isele naa si, ohun to wa ninu iwe lo ye ki won fi gbe, nigba teeyan ni So-Safe Corps loun, ti won wa fi  fijilante gbe e jade.

 Adedoyin tun ni awon ti ko leta sawon olopaa lori isele naa lati fehonu won han, igba akoko si ko ree, ti awon  maa n gbe iru igbese bee, tawon ba ri nnkan to ru won loju.

Bee lo ni  awon ati alaabo So Safe corps, ko mu ara won gege bi orogun, nitori oju orun tawona wo yii, o teye fo, lai kanra. Ki i se awon ki i jo sise, awon  jo maa n sise papo.  Awon ko nija laarin ara won, o ni bawon omo won ba jo pade, won ki i bara won ja. Sugbon tiru nnkan to sele yii ba waye, o ye kawon jo fi suuru yanju e ni. Nnkan to ba ti sele ti sele, ooto lo ye kawon maa so fawon araalu, ko ye kawon paro.

Pabanbari e lo ni ‘Nigba to di anaa, ni eni to je Baba Isale  wa, Balogun, ti won je komisanna ri, won fi atejise ranse si wa, ti won si bawa mejeeji soro, o ni ka fopin si bi a se taku oro so laarin ara wa. Latigba naa, la ti gbe igbese, ti gbogbo e ti niyanju.

No comments:

Post a Comment

Pages