Soji Ganzallo, oga
agba fun ileese alaabo So- Safe Corps, tipinle Ogun ni, ti so pe kantankantan
ni Nureni Adedoyin to je oga fawon fijilante
Naijiria so pe awon omo abe oun mo nipa bi won se pa omoleewe, oni ipele kerin,
ti yunifasiti Olabisi Onabanjo, ni Ijebu Igbo. O ni o kan fee fi bawon loruko
je ni.
Okunrin naa soro yii,
lakooko to n se ipade po pelu awon oniroyin lojo Eti, Furaidee, ose yii ni
ofiisi e, o ni oga fijilante naa kan n wona lati si ibaje awon ni,, .
O so pe gege bi awon
olopaa gan an se gbe jade, o fi han daju pea won meta towo naa te kii somo egbe
So- Safe Corps, tawon naa si jeri nipa e.
O ni oro naa lodi
gedegbe si nnkan ti oga awon fijilante Naijiria naa so. O tun fidi e mule pe
lojoruu, Wesidee, ti komisanna fawon olopaa nipinle Ogun safihan awon eeyan
naa, oun gan-an so pe awon meta towo te naa je omo egbe fijilante ibile ti won
pe ni ‘Yaluwon’, ti won ko si ni nnkankan se po pelu So- Safe Corps awon.
Gazallo so pe" Mo
fee mu da gbogbo awon eeyan loju awon meteeta ti won je jomo fijilante towo te
lori pe won pa omoleewe yunifasiti Olabisi Onabanjo ki I sawon osise wa So Safe
Corps",
Oniroyin wa beere lowo
Oga So- Safe Corps naa boya awon atenikan jo nija po, Okunrin naa so pe ko si
nnkan to jo sugbon o lo se ni laanu pea won fijilante ti Naijiria, ti Adedoyin
je oga won nipinle Ogun pe ipade oniroyin lati b awon loruko je pe osise awon
ni won mu fesun naa.
O ni "Nnkan to
sele yii nii se pelu awon olopaa, nitori awon lo safihan fawon oniroyin lojo
naa, ko si menuba pe osise So- Safe- Corps lawon mu’.
‘ O ni iyalenu lo je
fawon nigba tawon gbo pe olori awon fijilante pariwo pe osise So- Safe- Corps
ni won mu. O ni awon nigbagbo ninu ofin, awon yoo sig be igbese, o si se e se
kawon pejo ibaniloruko je.
O wa pari oro e pe
ajosepo to danmoran lo wa laarin egbe alaabo awon ati tawon olopaa, idi niyii
tawon fi jo n sise po fun eto abo ilu.
No comments:
Post a Comment