Awon Yoruba maa n soro kan, won a ni ko si bi eni eeyan se le dagba to, ti yoo gbadura pe ki iku muu lo, bi ki won saa maa ri ra won nigbakugba lo maa n ri.
Sugbon tiku ba ti wa mu
enikan lo lara ibara je yen maa n po, iru e lo sele si gbajumo osere alawada
nni, Afiz Oyetoro, topo mo si simply Saka, to bara je gidigidi, to si n wa ekun
mu lakooko ti won sin iya e to doloogbe.
Ki i se pe iya
naa,Adedewe Abike Apeteasa Oyetoro ko dagba, odun mejilelaadorun lo lo kolojo
to de sugbon eni to ba ri Afiz lojo naa yoo mo pe nnkan gidi lo lo ninu aye e
yii.
Gege bi a se gbo, Lojoruu,
Wesidee, ni mama naa dagbere faye pe o digbose nile e to wa ni Iseyin, nipinle
Oyo.
Irole ojo naa ni won sin
sinku mama naa nilana esin musulumi, gbogbo awon to wa nibe lojo naa ti
sapejuwe
Mama naa gege bi abiyamo tooto, to si tun je elesin titi dojo iku e.
Adura ojo mejo fun Mama
naa la gbo pe yoo waye Lojoruu, Wesidee, ose to n bo, niluu Iseyin.
No comments:
Post a Comment