Ofe la maa n yanju aawo, ijoba lo n sanwo wa- Shem Obafaiye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 30 August 2019

Ofe la maa n yanju aawo, ijoba lo n sanwo wa- Shem Obafaiye






  Oga agba patapata fajo alaabo ilu siifu lorileede yii, Muhammad Abdullahi Gana, ofe lawon to n pari ija tabi aawo ki alaafia le joba maa n sise won, nitori ijoba lo fawon lowo, awon ki i si beere owo lowo awon araalu.

Lojobo, Tosidee, lo soro yii ninu ise to ran, eyi ti olori sifu ni ekun F, Ogbeni Shem Obafaiye, je loruko e, nibi ayeye ikekoo jade awon abe won ti won ko nipa ona teeyan fi yanju aawo, ki alaafia le joba laarin awon eeyan, nibi tawon ogorin osise won jakejado orileede yii ti kopa,to waye niluu Abeokuta.

Okunrin naa so pe o le ni egberun metadinlogoji esun okan-o-jokan tawon ti yanju titi di akoko yii bee lawon si tun ti gba milionu lona igba naira lowo awon to n bara won ja.

Oga agba patapata naa tun fi kun oro e nipa riro awon araalu lati je ki ife ati alaafia joba, o ni oun ni ona kan soso to le je ki ogba ewon dinku.

O te siwaju pe idanilekoo yii se pataki ati pe oun nikan lona ti won le gba maa fi yanju ija gege bi won ti n se laye atijo.

 Obafaiye to n jise oga e lojo naa tun wa ro awon eeyan l  ojo naa pe ki won gba asoye laye gege ona to fopin si aawo laarin won.

O ni okan lara aabo araalu to se pataki ni ki won gba alaafia laye lori awon nnkan ini won ati pe nnkan eyo kan pataki ti idanilekoo naa wa fun ni gbigba alaafia laye lawujo.

O loun nigbagbo bi iru nnkan bee ba sele, ko ni si pe won gbe ara loo sewon tabi loo sile ejo, nitori awon Yoruba lo so pe ai ti kootu bo ka sore.


No comments:

Post a Comment

Pages