Ariwo tawon to wa nibi ayeye adura ojo mejo Alaaja Ayisatu Kehinde Odejinmi, to je Iya Suna, Ijemo Agbadu Ibon, niluu Abeokuta n pa ni pe oloore lo. Bee lawon ti ko le muu mora bu sekun pe awon ko tun ni ri iya naa mo.
Adura naa to
waye ni Wasinmi, Ake, niluu Abeokuta nile ebi Ologbonwo, lawon omo, ebi ati ore
ti pejo lawon ti wa sadura fun mama naa.
Ni nnkan bii
aago meta osan oni yii ni won se adura naa nibi tawon alaafa jakanjakan, to fi
mo imaamu ti pejupese nibi ayeye naa.
Bakan naa ni
Alaaji Akimu Odejinmi topo mo si Ologbonwo, to ti figba je alaga kansu nijoba
ibile Abeokuta South, atawon omo yooku fi adura ran mama won lowo pe ki Olorun
tee si afefe rere.
Ojo
kejilelogun, osu yii ni mama naa, dagbere faye leyin to ti lo odun
merindinlaadorun laye. Eyi ni die lara awon foto ayeye adura ojo mejo naa.
No comments:
Post a Comment