Ola, Ojobo, Tosidee, ni won yoo sayeye adura fidau fun Alaaja Ayisatu Kehinde Odejinmi, to je Iya Suna Ijemo Agbadu Ibon niluu Abeokuta.
Gege bi
atejade kan ti omo e, Alaaji Akimu Odejinmi topo mo si Ologbonwo, to ti figba
je alaga kansu nijoba ibile Abeokuta South fi sita, ile molebi won to wa ni
Wasinmi, Ake ni adura naa yoo ti waye bere ni dede aago mejila osan.
O fi kun oro
e pe gbogbo eto lo ti ti fayeye adura ojo mejo naa nibi tawon alaafa yoo ti wa
seto adura naa. Ojo kejilelogun, osu yii ni mama naa dagbere faye leyin to ti
lo odun merindinlaadorun laye.
Nigba to n
sapejuwe nipa Mama naa, Akimu Ologbonwo so pe eeyan jeje ni mama naa, to ko si
fesin sere, o ni elesin islam tooto ni mama oun, to si maa n fadura ran gbogbo
awon omo ati ebi lowo.
O tun fi kun
pe se lo maa n ya mama naa lenu pe se oun loun bi oun nitori bi iya naa se tutu
to, O ni ipa ti Mama naa ko laye oun ko kere. Omo mefa la gbo pe iya naa fi
saye lo.
No comments:
Post a Comment